1 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
1 OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:
1 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé:
Bayi ni awọn ọmọ Israeli si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.
Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn.
Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká.
Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá: