Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:9 - Bibeli Mimọ

9 Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ẹnìkan tí ó jẹ́ mímọ́ yóo kó eérú mààlúù náà jọ sí ibìkan tí ó mọ́ lẹ́yìn ibùdó. Eérú náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóo máa lò fún omi ìwẹ̀nùmọ́, fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:9
16 Iomraidhean Croise  

Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́.


LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́.


Ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn okú ẹnikan ti o kú, ti kò si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, o bà agọ́ OLUWA jẹ́; ọkàn na li a o si ke kuro ninu Israeli: nitoriti a kò wọ́n omi ìyasapakan si i lara, alaimọ́ li o jẹ̀; aimọ́ rẹ̀ mbẹ lara rẹ̀ sibẹ̀,


Ati fun ẹni aimọ́ kan ki nwọn ki o mú ninu ẽru sisun ẹbọ ẹ̀ṣẹ nì, ki a si bù omi ti nṣàn si i ninu ohun-èlo kan:


Ki ẹnikan ti o mọ́ ki o si mú hissopu, ki o si tẹ̀ ẹ bọ̀ inu omi na, ki o si fi i wọ́n agọ́ na, ati ohun-èlo gbogbo, ati sara awọn enia ti o wá nibẹ̀, ati sara ẹniti o fọwọkàn egungun kan, tabi ẹnikan ti a pa, tabi ẹnikan ti o kú, tabi isà-okú:


Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀:


Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ki o si yà ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀ simimọ́ si OLUWA, ki o si mú akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹbi: ṣugbọn ọjọ́ ti o ti ṣaju yio di asan, nitoripe ìyasapakan rẹ̀ bàjẹ́.


Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́.


Ṣugbọn ọkunrin na ti o mọ́ ti kò si sí li ọ̀na àjo, ti o si fàsẹhin lati pa irekọja mọ́, ani ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀: nitoriti kò mú ọrẹ-ẹbọ OLUWA wá li akokò rẹ̀, ọkunrin na yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.


Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.


NITORINA, ẹnyin olufẹ, bi a ti ni ileri wọnyi, ẹ jẹ ki a wẹ̀ ara wa mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin ti ara ati ti ẹmí, ki a mã sọ ìwa mimọ́ di pipé ni ìbẹru Ọlọrun.


Nitoripe irú Olori Alufa bẹ̃ li o yẹ wa, mimọ́, ailẹgan, ailẽri, ti a yà si ọ̀tọ kuro ninu ẹlẹṣẹ, ti a si gbéga jù awọn ọrun lọ;


Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan