Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:7 - Bibeli Mimọ

7 Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:7
19 Iomraidhean Croise  

Nitori wọnyi li ẹnyin o si jẹ́ alaimọ́: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ:


Ẹnikẹni ti o ba si rù ohun kan ninu okú wọn ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ati ohunkohun ti o ba si nrìn lori ẽkanna rẹ̀, ninu gbogbo onirũru ẹranko, ti nfi ẹsẹ̀ mẹrẹrin rìn, alaimọ́ ni nwọn fun nyin: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ẹniti o ba si rù okú wọn ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: alaimọ́ ni nwọn fun nyin.


Wọnyi li alaimọ́ fun nyin ninu gbogbo ohun ti nrakò: ẹnikẹni ti o ba farakàn okú wọn, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ati lara ohunkohun ti okú wọn ba ṣubulù, ki o jasi alaimọ́; ibaṣe ohun èlo-igi, tabi aṣọ, tabi awọ, tabi àpo, ohunèlo ti o wù ki o ṣe, ninu eyiti a nṣe iṣẹ kan, a kò gbọdọ má fi bọ̀ inu omi, on o si jasi alaimọ́ titi di aṣalẹ; bẹ̃li a o si sọ ọ di mimọ́.


Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ẹniti o ba si wọ̀ ile na ni gbogbo ìgba na ti a sé e mọ́, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ọkàn ti o ba farakàn ọkan ninu irú ohun bẹ̃ ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ, ki o má si ṣe jẹ ninu ohun mimọ́, bikoṣepe o ba fi omi wẹ̀ ara rẹ̀.


Ki ẹniti o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: yio si jẹ́ ilana titilai, fun awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.


Ki ẹniti o mọ́ na ki o si bùwọ́n alaimọ́ na ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje: ati ni ijọ́ keje ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́; ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omì, yio si di mimọ́ li aṣalẹ.


Yio si ma jẹ́ ìlana lailai fun wọn, pe ẹniti o ba bú omi ìyasapakan wọ́n ẹni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀; ati ẹniti o si fọwọkàn omi ìyasapakan na yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ati ohunkohun ti ẹni aimọ́ na ba si farakàn, yio jẹ́ alaimọ́; ọkàn ti o ba si farakàn a, yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Ki ẹniti o sun u ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀ ninu omi, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.


Nitoripe ara awọn ẹran wọnni, ẹ̀jẹ eyiti olori alufa mu wá si ibi mimọ́ nitori ẹ̀ṣẹ, a sun wọn lẹhin ibudo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan