Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:3 - Bibeli Mimọ

3 Ki ẹnyin si fi i fun Eleasari alufa, ki on ki o mú u jade lọ sẹhin ibudó, ki ẹnikan ki o si pa a niwaju rẹ̀:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 O óo fún Eleasari alufaa, yóo mú un lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, wọn óo sì pa á níbẹ̀ níṣojú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:3
11 Iomraidhean Croise  

Ati akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ewurẹ nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ẹ̀jẹ eyiti a múwa lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ni ki ẹnikan ki o mú jade lọ sẹhin ode ibudó; ki nwọn ki o si sun awọ wọn, ati ẹran wọn, ati igbẹ́ wọn ninu iná.


Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta.


Ati awọ akọmalu na, ati gbogbo ẹran rẹ̀, pẹlu ori rẹ̀, ati pẹlu itan rẹ̀, ati ifun rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀,


Ani gbogbo akọmalu na ni ki o mú jade lọ sẹhin ibudó si ibi mimọ́ kan, ni ibi ti a ndà ẽru si, ki o si fi iná sun u lori igi: ni ibi ti a ndà ẽru si ni ki a sun u.


Ki o si gbé akọmalu na jade lọ sẹhin ibudó, ki o si sun u bi o ti sun akọmalu iṣaju: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni fun ijọ enia.


Gbogbo ijọ si mú u wá sẹhin ibudó, nwọn si sọ ọ li okuta, on si kú; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


Ki ọkunrin kan ti o mọ́ ki o si kó ẽru ẹgbọrọ abomalu na, ki o si kó o jọ si ibi kan ti o mọ́ lẹhin ibudó, ki a si pa a mọ́ fun ijọ awọn ọmọ Israeli fun omi ìyasapakan: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.


Nadabu ati Abihu si kú niwaju OLUWA, nigbati nwọn rubọ iná àjeji niwaju OLUWA ni ijù Sinai, nwọn kò si lí ọmọ: ati Eleasari ati Itamari nṣe iṣẹ alufa niwaju Aaroni baba wọn.


Paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o yọ gbogbo adẹ̀tẹ kuro ni ibudó, ati gbogbo ẹniti o ní isun, ati ẹnikẹni ti o di alaimọ́ nipa okú:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan