Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:12 - Bibeli Mimọ

12 Ki oluwarẹ̀ ki o fi i wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́ ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje yio di mimọ́: ṣugbọn bi kò ba wẹ̀ ara rẹ̀ ni ijọ́ kẹta, njẹ ni ijọ́ keje ki yio di mimọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, yóo wẹ ara rẹ̀ pẹlu omi ìwẹ̀nùmọ́, yóo sì di mímọ́. Kò ní di mímọ́ bí kò bá wẹ ara rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:12
12 Iomraidhean Croise  

Fi ewe-hissopu fọ̀ mi, emi o si mọ́: wẹ̀ mi, emi o si fún jù ẹ̀gbọn-owu lọ.


Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo.


O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin.


Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin.


Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀.


Ki o si fi wọ́n ẹniti a o wẹ̀numọ́ kuro ninu ẹ̀tẹ nigba meje, ki o si pè e ni mimọ́, ki o si jọwọ ẹiyẹ alãye nì lọwọ lọ si gbangba oko.


Ṣugbọn iyokù ninu ẹran ẹbọ na ni ijọ́ kẹta ni ki a fi iná sun.


Ki ẹnyin ki o si duro lẹhin ibudó ni ijọ meje: ẹnikẹni ti o ba pa enia, ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ẹniti a pa, ki ẹnyin si wẹ̀ ara nyin mọ́, ati ara awọn igbẹsin nyin ni ijọ́ kẹta, ati ni ijọ́ keje.


Kò si fi iyatọ si ãrin awa ati awọn, o nfi igbagbọ́ wẹ̀ wọn li ọkàn mọ́.


Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan