Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:9 - Bibeli Mimọ

9 Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ninu gbogbo ẹbọ mímọ́ tí a kò sun lórí pẹpẹ, ẹbọ ọrẹ, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí wọn ń rú sí mi yóo jẹ́ mímọ́ jùlọ fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpín wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:9
24 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Hasaeli ọba Siria gòke lọ, o si ba Gati jà, o si kó o: Hasaeli si doju rẹ̀ kọ ati gòke lọ si Jerusalemu.


Pẹlu akọbi awọn ọmọ wa ọkunrin, ati ti ohun ọ̀sin wa, gẹgẹ bi ati kọ ninu ofin, akọbi awọn ẹran-nla wa, ati ti agutan wa, lati mu wọn wá si ile Ọlọrun wa, fun awọn alufa ti nṣiṣẹ ni ile Ọlọrun wa.


O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.


Awọn ni yio jẹ ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; ati gbogbo ohun-egún ni Israeli, yio jẹ́ ti wọn.


Nitori kini ẹnyin kò ṣe jẹ ẹbọ èṣẹ na ni ibi mimọ́, nitoripe mimọ́ julọ ni, a si ti fi fun nyin lati rù ẹ̀ṣẹ ijọ enia, lati ṣètutu fun wọn niwaju OLUWA?


Ki o si pa akọ ọdọ-agutan na ni ibiti on o gbé pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ ati ẹbọ sisun, ní ibi mimọ́ nì: nitoripe bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti jẹ́ ti alufa, bẹ̃ si ni ẹbọ irekọja: mimọ́ julọ ni:


Eyiti o si kù ninu ẹbọ ohunjijẹ, ki o jẹ́ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni, ọrẹ-ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe.


Ṣugbọn bi alufa ba fi owo rẹ̀ rà ẹnikan, ki o jẹ ninu rẹ̀; ẹniti a si bi ninu ile rẹ̀, ki nwọn ki o ma jẹ ninu onjẹ rẹ̀.


Nigbati õrùn ba si wọ̀, on o di mimọ́; lẹhin eyinì ki o si ma jẹ ninu ohun mimọ́, nitoripe onjẹ rẹ̀ ni.


Nigbati ijoye kan ba ṣẹ̀, ti o si fi aimọ̀ rú ọkan ninu ofin OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ti a ki ba rú, ti o si jẹbi;


Bi ọkan ninu awọn enia ilẹ na ba fi aimọ̀ sẹ̀, nigbati o ba ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA ti a ki ba ṣe, ti o si jẹbi;


BI ẹnikan ba si ṣẹ̀, ti o si gbọ́ ohùn ibura, ti o si ṣe ẹlẹri, bi on ba ri tabi bi on ba mọ̀, ti kò ba wi, njẹ ki o rù aiṣedede rẹ̀.


Ki o si mú ẹbọ ẹbi rẹ̀ wá fun OLUWA, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀, abo lati inu agbo-ẹran wá, ọdọ-agutan tabi ọmọ ewurẹ kan, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ; ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.


Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Kò si sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ kan, ẹ̀jẹ eyiti a múwa sinu agọ́ ajọ, lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ti a gbọdọ jẹ: sisun ni ki a sun u ninu iná.


EYI si li ofin ẹbọ ẹbi: mimọ́ julọ ni.


Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni.


Bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ si li ẹbọ ẹbi: ofin kan ni fun wọn: alufa ti nfi i ṣètutu ni ki on ní i.


Bi ohun mimọ́ julọ ni ki iwọ ki o ma jẹ ẹ: gbogbo ọkunrin ni yio jẹ ẹ; mimọ́ ni yio jẹ́ fun ọ.


AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan