Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:8 - Bibeli Mimọ

8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Mo ti fún ọ ní gbogbo ohun tí ó kù ninu àwọn ohun tí wọ́n bá fi rúbọ sí mi, ati gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni mo fún gẹ́gẹ́ bi ìpín yín títí lae.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdí gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:8
32 Iomraidhean Croise  

Owo ẹbọ irekọja ati owo ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni a kò mu wá sinu ile Oluwa: ti awọn alufa ni.


Pẹlupẹlu o paṣẹ fun awọn enia ti ngbe Jerusalemu lati fi ipin kan fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin.


Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ.


Nwọn o si wà lara Aaroni, ati lara awọn ọmọ rẹ̀, nigbati nwọn ba wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, tabi nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ, lati ṣiṣẹ ni ibi mimọ́; ki nwọn ki o má ba dẹ̀ṣẹ, nwọn a si kú: ìlana lailai ni fun u ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.


Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.


Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA.


Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn.


Iwọ o si fi aṣọ mimọ́ wọnni wọ̀ Aaroni; iwọ o si ta oróro si i li ori, iwọ o si yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.


Iwọ o si ta oróro si wọn li ori, bi iwọ ti ta si baba wọn li ori, ki nwọn ko le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi: nitoriti itasori wọn yio jẹ́ iṣẹ-alufa lailai nitõtọ, lati irandiran wọn.


Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbe ẹrù rẹ̀ kuro li ejika rẹ, ati àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ, a o si ba àjaga na jẹ ní ọrùn rẹ.


Ati olori alufa ninu awọn arakunrin rẹ̀, ori ẹniti a dà oróro itasori si, ti a si yàsọtọ lati ma wọ̀ aṣọ wọnni, ki o máṣe ṣi ibori rẹ̀, tabi ki o fà aṣọ rẹ̀ ya;


Ki alufa ki o si fi wọn pẹlu àkara àwọn akọ́so fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA, pẹlu ọdọ-agutan meji nì: ki nwọn ki o si jẹ́ mimọ́ si OLUWA fun alufa na.


Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ.


Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́.


Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ.


Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ.


Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Gbogbo ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: ni ibi mimọ́ kan ki a jẹ ẹ: mimọ́ julọ ni.


Mose si mú ninu oróro itasori nì, ati ninu ẹ̀jẹ ti mbẹ lori pẹpẹ, o si fi i wọ́n ara Aaroni, ati ara aṣọ rẹ̀ wọnni, ati ara awọn ọmọ rẹ̀, ati ara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀; o si yà Aaroni simimọ́, ati aṣọ rẹ̀ wọnni, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.


Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ.


Ati gbogbo ẹbọ agbesọsoke ohun mimọ́ gbogbo ti awọn ọmọ Israeli, ti nwọn mú tọ̀ alufa wá, yio jẹ́ tirẹ̀.


Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ?


Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA.


Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o ma mú ẹbọ sisun nyin wá, ati ẹbọ nyin, ati idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ifẹ́-atinuwa nyin, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran nyin ati ti agbo-ẹran nyin:


AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.


Nigbana ni ki iwọ ki o wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Emi ti mú ohun mimọ́ kuro ninu ile mi, mo si ti fi wọn fun ọmọ Lefi, ati fun alejò, ati fun alainibaba, ati fun opó, gẹgẹ bi gbogbo aṣẹ rẹ ti iwọ ti pa fun mi: emi kò re aṣẹ rẹ kọja, bẹ̃li emi kò gbagbé wọn:


Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ.


Ṣugbọn ẹnyin ni ifororo-yan lati ọdọ Ẹni Mimọ́ nì wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo.


Ṣugbọn ìfororó-yàn ti ẹnyin ti gbà lọwọ rẹ̀, o ngbe inu nyin, ẹnyin kò si ni pe ẹnikan nkọ́ nyin: ṣugbọn ìfororó-yàn na nkọ́ nyin li ohun gbogbo ti o jẹ otitọ, ti kì si iṣe èké, ani gẹgẹ bi o si ti kọ́ nyin, ẹ mã gbe inu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan