Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:6 - Bibeli Mimọ

6 Ati emi, kiyesi i, mo ti mú awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli: ẹnyin li a fi wọn fun bi ẹ̀bun fun OLUWA, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Mo ti yan àwọn eniyan rẹ, àwọn ọmọ Lefi, láàrin àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọ. Wọ́n jẹ́ ẹ̀bùn fún OLUWA, wọn óo sì máa ṣiṣẹ́ ninu Àgọ́ Àjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Èmi fúnra mi ti yan àwọn arákùnrin rẹ tí í ṣe ọmọ Lefi kún àwọn ọmọ Israẹli yòókù, wọn jẹ́ ẹ̀bùn fún ọ, èyí ni a fún Olúwa láti ṣe iṣẹ́ tí ó wà ní àgọ́ ìpàdé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:6
14 Iomraidhean Croise  

Ati emi, wò o, emi nmu kikun-omi bọ̀ wá si aiye, lati pa gbogbo ohun alãye run, ti o li ẹmi ãye ninu kuro labẹ ọrun; ohun gbogbo ti o wà li aiye ni yio si kú.


Ati emi, kiye si i, emi ba nyin dá majẹmu mi, ati awọn irú-ọmọ nyin lẹhin nyin;


Ati emi kiyesi i, emi o mu àiya awọn ara Egipti le, nwọn o si tẹle wọn: a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori gbogbo ogun rẹ̀, ati lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀.


Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:


Emi, ani emi ti sọ ọ; lõtọ emi ti pè e: emi ti mu u wá, on o si mu ọ̀na rẹ̀ ṣe dẽde.


Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko.


Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri.


Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi, emi, ani emi, o ṣe idajọ lãrin ọwọ́-ẹran ti o sanra, ati eyiti o rù.


Ati emi, kiyesi i, emi ti gbà awọn ọmọ Lefi kuro lãrin awọn ọmọ Israeli ni ipò gbogbo akọ́bi ti o ṣí inu ninu awọn ọmọ Israeli; nitorina ti emi li awọn ọmọ Lefi iṣe:


Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi; nitoripe li ọjọ́ na ti mo kọlù gbogbo akọ́bi ni ilẹ Egipti, ni mo yà gbogbo akọ́bi sọ̀tọ fun ara mi ni Israeli, ati enia ati ẹran: ti emi ni nwọn o ma ṣe: Emi li OLUWA.


Gbà awọn ọmọ Lefi ni ipò gbogbo awọn akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ohun-ọ̀sin awọn ọmọ Lefi nipò ohun-ọ̀sin wọn; awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi; Emi li OLUWA.


Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.


Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan