Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:12 - Bibeli Mimọ

12 Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 “Mo fún ọ ní gbogbo èso àkọ́so tí àwọn ọmọ Israẹli ń mú wá fún mi lọdọọdun, ati òróró tí ó dára jùlọ, ọtí waini tí ó dára jùlọ, ati ọkà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:12
19 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun yio si fun ọ ninu ìri ọrun, ati ninu ọrá ilẹ, ati ọ̀pọlọpọ ọkà ati ọti-waini:


Ọkunrin kan si ti Baali-Ṣaliṣa wá, o si mu àkara akọso-eso, ogun iṣu àkara barle, ati ṣiri ọkà titun ninu àpo rẹ̀ wá fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ.


Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ.


O fi alafia ṣe àgbegbe rẹ, o si fi alikama didara-jù kún ọ.


Alikama daradara ni on iba ma fi bọ́ wọn pẹlu: ati oyin inu apata ni emi iba si ma fi tẹ́ ọ lọrun.


Iwọ kò gbọdọ jafara lati mú irè oko rẹ wá, ati ọti rẹ. Akọ́bi awọn ọmọ rẹ ọkunrin ni iwọ o fi fun mi.


Akọ́ka eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o múwa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.


Akọ́so eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o mú wa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.


Ati ikini ninu gbogbo akọ́so nkan gbogbo, olukuluku ọrẹ gbogbo, ninu gbogbo ọrẹ nyin, yio jẹ ti awọn alufa: ẹ o si fi akọ́po iyẹfun nyin fun alufa, ki ibukun le bà le ile rẹ.


Bi ọrẹ-ẹbọ akọ́so, ẹnyin le mú wọn wá fun OLUWA: ṣugbọn a ki yio sun wọn lori pẹpẹ fun õrùn didùn.


Bi iwọ ba si mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá fun OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà daradara ti a yan lori iná wá fun ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ, ọkà gigún, ti ṣiri tutù.


Ki ẹnyin ki o si mú lati inu ibugbé nyin wá, ìṣu-àkara fifì meji ti idamẹwa meji òṣuwọn: ki nwọn ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara, ki a fi iwukàra yan wọn, akọ́so ni nwọn fun OLUWA.


Ki alufa ki o si fi wọn pẹlu àkara àwọn akọ́so fun ẹbọ fifì niwaju OLUWA, pẹlu ọdọ-agutan meji nì: ki nwọn ki o si jẹ́ mimọ́ si OLUWA fun alufa na.


Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo.


Akọ́so ọkà rẹ pẹlu, ati ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́rẹ irun agutan rẹ, ni ki iwọ ki o fi fun u.


Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.


Ori-amọ́ malu, ati warà agutan, pẹlu ọrá ọdọ-agutan, ati àgbo irú ti Baṣani, ati ewurẹ, ti on ti ọrá iwe alikama; iwọ si mu ẹ̀jẹ eso-àjara, ani ọti-waini.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan