Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:8 - Bibeli Mimọ

8 O si ṣe, ni ijọ́ keji ti Mose wọ̀ inu agọ́ ẹrí lọ; si kiyesi i, ọpá Aaroni fun ile Lefi rudi, o si tú, o si tanna, o si so eso almondi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó wọ inú Àgọ́ Ẹ̀rí ní ọjọ́ keji, ó rí i pé ọ̀pá Aaroni tí ó wà fún ẹ̀yà Lefi ti rúwé, ó ti tanná, ó ti so èso alimọndi, èso náà sì ti pọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì Mose wọ inú àgọ́ ẹ̀rí lọ, ó sì rí ọ̀pá Aaroni, tí ó dúró fún ẹ̀yà Lefi, kì í ṣe wí pé ó hù nìkan Ṣùgbọ́n ó rúwé, ó yọ ìtànná, ó sì so èso almondi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:8
13 Iomraidhean Croise  

Ati lara àjara na li ẹka mẹta wà; o si rudi, itana rẹ̀ si tú jade; ati ṣiri rẹ̀ si so eso-ájara ti o pọ́n.


Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ.


Bi igi eleso lãrin awọn igi igbẹ, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọkunrin. Emi fi ayọ̀ nla joko labẹ ojiji rẹ̀, eso rẹ̀ si dùn mọ mi li ẹnu.


Li ọjọ na ni ẹka Oluwa yio ni ẹwà on ogo, eso ilẹ yio si ni ọla, yio si dara fun awọn ti o sálà ni Israeli.


Gbogbo igi inu igbẹ ni yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti mu igi giga walẹ, ti mo ti gbe igi rirẹlẹ soke, ti mo ti mu igi tutù gbẹ, ti mo si ti mu igi gbigbẹ ruwé: emi Oluwa li o ti sọ ti mo si ti ṣe e.


Ṣugbọn a fã a tu ni irúnu, a wọ ọ lulẹ, ẹfũfu ila-õrun si gbe eso rẹ̀, ọpá lile rẹ̀ ti ṣẹ, o si rọ; iná jo o run.


Iná si jade lati inu ọpá kan ninu ẹka rẹ̀, ti o ti jo eso rẹ̀ run, tobẹ̃ ti kò fi ni ẹka ti o le lati ṣe ọpa lati joye. Eyi ni ohùnrére ẹkun, yio si jẹ ohùn-rére ẹkun.


O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀.


Yio si ṣe, ọpá ẹniti emi o yàn yio ruwe: emi o si da kikùn awọn ọmọ Israeli duro kuro lọdọ mi, ti nwọn nkùn si nyin.


Mose si kó gbogbo ọpá na lati iwaju OLUWA jade tọ̀ gbogbo awọn ọmọ Israeli wá: nwọn si wò, olukuluku si mú ọpá tirẹ̀.


Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan