Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:7 - Bibeli Mimọ

7 Mose si fi ọpá wọnni lelẹ niwaju OLUWA ninu agọ́ ẹrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Mose kó gbogbo àwọn ọ̀pá náà siwaju OLUWA ninu Àgọ́ Ẹ̀rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Mose sì fi ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú Olúwa nínú àgọ́ ẹ̀rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:7
9 Iomraidhean Croise  

Eyi ni iye agọ́ na, agọ́ ẹrí nì, bi a ti kà wọn, gẹgẹ bi ofin Mose, fun ìrin awọn ọmọ Lefi, lati ọwọ́ Itamari wá, ọmọ Aaroni alufa.


Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ érí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: awọn ni ki o ma rù agọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; awọn ni yio si ma ṣe iṣẹ-ìsin rẹ̀, ki nwọn ki o si dó yi agọ́ na ká.


Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na.


Gbogbo ijọ si wipe ki a sọ wọn li okuta. Ṣugbọn ogo OLUWA hàn ninu agọ́ ajọ niwaju gbogbo awọn ọmọ Israeli.


Ki o si fi wọn lelẹ ninu agọ́ ajọ, niwaju ẹrí, nibiti emi o gbé pade nyin.


Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn olori wọn si fun u li ọpá, ọpá kan fun olori kan, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, ani ọpá mejila: ọpá Aaroni si wà ninu ọpá wọn.


Ati awọn arakunrin rẹ pẹlu, ẹ̀ya Lefi, ẹ̀ya baba rẹ, ni ki o múwa pẹlu rẹ, ki nwọn ki o le dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ fun ọ: ṣugbọn iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio ma ṣe iranṣẹ niwaju agọ́ ẹrí.


Ati li ọjọ́ ti a gbé agọ́ ró awọsanma si bò agọ́ na, eyinì ni, agọ́ ẹrí: ati li alẹ o si hàn lori agọ́ na bi iná, titi o fi di owurọ̀.


Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan