Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:2 - Bibeli Mimọ

2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si gbà ọpá kọkan lọwọ wọn, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, lọwọ gbogbo awọn olori wọn gẹgẹ bi ile awọn baba wọn ọpá mejila: ki o si kọ́ orukọ olukuluku si ara ọpá rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 “Gba ọ̀pá mejila láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀pá kọ̀ọ̀kan láti ọwọ́ olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ orúkọ olukuluku sí ara ọ̀pá tirẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:2
18 Iomraidhean Croise  

Ọpá-alade ki yio ti ọwọ́ Judah kuro, bẹ̃li olofin ki yio kuro lãrin ẹsẹ̀ rẹ̀, titi Ṣiloh yio fi dé; on li awọn enia yio gbọ́ tirẹ̀.


Ati fun awọn alufa ti a kọ sinu iwe nipa ile baba wọn, ati awọn ọmọ Lefi, lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ, ninu ilana wọn, nipa ipa wọn:


Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ.


Nitori ti ọpá awọn enia buburu kì yio bà le ipin awọn olododo: ki awọn olododo ki o má ba fi ọwọ wọn le ẹ̀ṣẹ.


Iwọ o si ta ninu rẹ̀ sara agọ́ ajọ, ati apoti ẹrí nì,


Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi.


OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni.


Iná si jade lati inu ọpá kan ninu ẹka rẹ̀, ti o ti jo eso rẹ̀ run, tobẹ̃ ti kò fi ni ẹka ti o le lati ṣe ọpa lati joye. Eyi ni ohùnrére ẹkun, yio si jẹ ohùn-rére ẹkun.


A pọ́n ọ lati pa enia pupọ; a dán a lati ma kọ màna: awa o ha ma ṣe ariyá? ọgọ ọmọ mi, o gàn gbogbo igi.


Nitoripe idanwo ni, ki si ni bi idà na gàn ọgọ na? kì yio si mọ́, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Fi ọpa rẹ bọ́ enia agbo ini rẹ, ti ndágbe inu igbó lãrin Karmeli: jẹ ki wọn jẹ̀ ni Baṣani ati Gileadi, bi ọjọ igbãni.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Ki o si kọ orukọ Aaroni sara ọpá Lefi: nitoripe ọpá kan yio jẹ́ fun ori ile awọn baba wọn.


OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan