Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 17:10 - Bibeli Mimọ

10 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú ọpá Aaroni pada wa siwaju ẹrí, lati fi pamọ́ fun àmi fun awọn ọlọ̀tẹ nì; ki iwọ ki o si gbà kikùn wọn kuro lọdọ mi patapata ki nwọn ki o má ba kú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 OLUWA sọ fún Mose, pé, “Dá ọ̀pá Aaroni pada siwaju Àpótí Ẹ̀rí, kí ó lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ Israẹli, kí wọ́n sì lè dẹ́kun kíkùn tí wọn ń kùn sí mi, kí wọ́n má baà kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí ààmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 17:10
23 Iomraidhean Croise  

Ọkàn mi wà lãrin awọn kiniun: emi tilẹ dubulẹ lãrin awọn ti o gbiná, eyinì ni awọn ọmọ enia, ehín ẹniti iṣe ọ̀kọ ati ọfa, ati ahọn wọn, idà mimú.


Mose si wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, Ẹ kún òṣuwọn omeri kan ninu rẹ̀ lati pamọ́ fun irandiran nyin; ki nwọn ki o le ma ri onjẹ ti mo fi bọ́ nyin ni ijù, nigbati mo mú nyin jade kuro ni ilẹ Egipti.


Bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃li Aaroni gbé e kalẹ niwaju ibi Ẹrí lati pa a mọ́.


Gbọ́, ẹnyin ọrun, si fi eti silẹ, iwọ aiye: nitori Oluwa ti sọ̀rọ, emi ti bọ́, emi si ti tọ́ awọn ọmọ, nwọn si ti ṣọ̀tẹ si mi.


Lati ọjọ Gibea ni iwọ ti ṣẹ̀, Israeli: nibẹ̀ ni nwọn duro: ogun Gibea si awọn ọmọ ẹ̀ṣẹ kò ha le wọn ba?


Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli.


Ẹ yà ara nyin kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣéju kan.


Awo-turari ti awọn ẹlẹṣẹ wọnyi si ọkàn ara wọn, ni ki nwọn ki o fi ṣe awo fẹlẹfẹlẹ fun ibori pẹpẹ: nitoriti nwọn mú wọn wá siwaju OLUWA, nitorina ni nwọn ṣe jẹ́ mimọ́: nwọn o si ma ṣe àmi fun awọn ọmọ Israeli.


Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.


Mose si ṣe bẹ̃: bi OLUWA ti fi aṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe.


Ki o si fi wọn lelẹ ninu agọ́ ajọ, niwaju ẹrí, nibiti emi o gbé pade nyin.


Mose si kó gbogbo ọpá na lati iwaju OLUWA jade tọ̀ gbogbo awọn ọmọ Israeli wá: nwọn si wò, olukuluku si mú ọpá tirẹ̀.


Mose si mú ọpá na lati iwaju OLUWA lọ, bi o ti fun u li aṣẹ.


Ẹ máṣe ke ẹ̀ya idile awọn ọmọ Kohati kuro lãrin awọn ọmọ Lefi:


Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn.


Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi ọ̀rọ asan tàn nyin jẹ: nitori nipasẹ nkan wọnyi ibinu Ọlọrun mbọ̀ wá sori awọn ọmọ alaigbọran.


Ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA lati ọjọ́ ti mo ti mọ̀ nyin.


Ranti, máṣe gbagbé, bi iwọ ti mu OLUWA Ọlọrun rẹ binu li aginjù: lati ọjọ́ na ti iwọ ti jade kuro ni ilẹ Egipti, titi ẹnyin fi dé ihin yi, ẹnyin ti nṣọ̀tẹ si OLUWA.


Ti o ni awo turari wura, ati apoti majẹmu ti a fi wura bò yiká, ninu eyi ti ikoko wura ti o ni manna gbé wà, ati ọpá Aaroni ti o rudi, ati awọn walã majẹmu;


Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ Oluwa.


Gbogbo awọn enia buburu ati awọn ọmọ Beliali ninu awọn ti o ba Dafidi lọ si dahun, nwọn si wipe, Bi nwọn kò ti ba wa lọ, a kì yio fi nkan kan fun wọn ninu ikogun ti awa rí gbà bikoṣe obinrin olukuluku wọn, ati ọmọ wọn; ki nwọn ki o si mu wọn, ki nwọn si ma lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan