Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:9 - Bibeli Mimọ

9 Ohun kekere ha ni li oju nyin, ti Ọlọrun Israeli yà nyin kuro ninu ijọ Israeli, lati mú nyin sunmọ ọdọ ara rẹ̀ lati ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ OLUWA, ati lati ma duro niwaju ijọ lati ma ṣe iranṣẹ fun wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Ṣé nǹkan kékeré ni, pé Ọlọrun Israẹli yà yín sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ OLUWA, ati fún ìjọ eniyan Israẹli?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Israẹli ti yà yín sọ́tọ̀ lára ìjọ Israẹli yòókù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ Olúwa àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:9
20 Iomraidhean Croise  

O si wi fun u pe, Iṣe nkan kekere ti iwọ gbà ọkọ lọwọ mi? iwọ si nfẹ́ gbà mandraki ọmọ mi pẹlu? Rakeli si wipe, Nitori na ni yio ṣe sùn tì ọ li alẹ yi nitori mandraki ọmọ rẹ.


Nkan kekere li eyi sa jasi li oju rẹ, Oluwa Ọlọrun; iwọ si sọ ti idile iranṣẹ rẹ pẹlu ni ti akoko ti o jina. Eyi ha ṣe ìwa enia bi, Oluwa Ọlọrun?


O si wi fun awọn ọmọ Lefi ti nkọ́ gbogbo Israeli, ti iṣe mimọ́ si Oluwa pe, Ẹ gbé apoti-ẹri mimọ́ nì lọ sinu ile na ti Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, ti kọ́; kì yio jẹ ẹrù li ejika mọ́: ẹ sìn Oluwa Ọlọrun nyin nisisiyi, ati Israeli, awọn enia rẹ̀;


Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro.


On si wipe, Ẹ gbọ́ nisisiyi ẹnyin ara ile Dafidi, iṣe ohun kekere fun nyin lati dá enia lagara, ṣugbọn ẹnyin o ha si dá Ọlọrun mi lagara pẹlu bi?


Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ?


Awọn ni yio wá si ibi-mimọ́ mi, awọn ni o si sunmọ tabili mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si pa ibi-iṣọ́ mi mọ́.


Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na.


Ohun kekere ha ni ti iwọ mú wa gòke lati ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin wá, lati pa wa li aginjù, ti iwọ fi ara rẹ jẹ́ alade lori wa patapata?


Mose si wi fun Kora pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹnyin ọmọ Lefi, ẹ gbọ́:


Mú ẹ̀ya Lefi sunmọtosi, ki o si mú wọn wá siwaju Aaroni alufa, ki nwọn le ma ṣe iranṣẹ fun u.


Ki iwọ ki o si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀: patapata li a fi wọn fun u ninu awọn ọmọ Israeli.


Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si.


Ṣugbọn, ohun kikini ni fun mi pe, ki ẹ mã ṣe idajọ mi, tabi ki a mã ṣe idajọ mi nipa idajọ enia: nitotọ emi kò ṣe idajọ emi tikarami.


Nigbana li OLUWA yà ẹ̀ya Lefi sọ̀tọ, lati ma rù apoti majẹmu OLUWA, lati ma duro niwaju OLUWA lati ma ṣe iranṣẹ fun u, ati lati ma sure li orukọ rẹ̀, titi di oni yi.


Awọn iranṣẹ Saulu si sọ̀rọ wọnni li eti Dafidi. Dafidi si wipe, O ha ṣe nkan ti o fẹrẹ loju nyin lati jẹ ana ọba? Talaka li emi ati ẹni ti a kò kà si.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan