O si ṣe, nigbati nwọn npa wọn, ti a si fi emi silẹ, mo da oju mi bo ilẹ, mo si kigbe, mo si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha pa gbogbo awọn iyokù Israeli run, nipa dida irúnu rẹ jade sori Jerusalemu?
O si sọ fun Kora ati fun gbogbo ẹgbẹ rẹ̀ pe, Li ọla OLUWA yio fi ẹniti iṣe tirẹ̀ hàn, ati ẹniti o mọ́; yio si mu u sunmọ ọdọ rẹ̀: ani ẹniti on ba yàn ni yio mu sunmọ ọdọ rẹ̀.