Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 16:11 - Bibeli Mimọ

11 Nitorina, iwọ ati gbogbo ẹgbẹ rẹ kójọ pọ̀ si OLUWA: ati kini Aaroni, ti ẹnyin nkùn si i?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Olúwa ni ìwọ àti gbogbo ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Aaroni jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 16:11
15 Iomraidhean Croise  

Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.


Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa.


Nitorina li awọn enia na ṣe mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Fun wa li omi ki a mu. Mose si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbà mi sọ̀? ẽṣe ti ẹnyin fi ndán OLUWA wò?


AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na.


Mose si ranṣẹ pè Datani ati Abiramu, awọn ọmọ Eliabu: nwọn si wipe, Awa ki yio gòke wá:


Nwọn si kó ara wọn jọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, nwọn si wi fun wọn pe, O tó gẹ, nitoripe gbogbo ijọ li o jẹ́ mimọ́, olukuluku wọn, OLUWA si mbẹ lãrin wọn: nitori kili ẹnyin ha ṣe ngbé ara nyin ga jù ijọ OLUWA lọ?


Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà ẹnikẹni ti mo rán, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi o gbà ẹniti o rán mi.


Nigbati o wà nibẹ, tirẹ ki iṣe? nigbati a si ta a tan, kò ha wà ni ikawọ ara rẹ? Ẽha ti ṣe ti iwọ fi rò kini yi li ọkàn rẹ? enia ki iwọ ṣeke si bikoṣe si Ọlọrun.


Nitorina ẹniti o ba tapá si aṣẹ, o tapá si ìlana Ọlọrun: awọn ẹniti o ba si ntapá, yio gbà ẹbi fun ara wọn.


Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn.


Kini Apollo ha jẹ? kini Paulu si jẹ? bikoṣe awọn iranṣẹ nipasẹ ẹniti ẹnyin ti gbagbọ́, ati olukuluku gẹgẹ bi Oluwa ti fun.


Awọn wọnyi li awọn ti nkùn, awọn alaroye, ti nrìn nipa ifẹkufẹ ara wọn; ẹnu wọn a mã sọ ọ̀rọ ìhalẹ, nwọn a mã ṣojuṣãjú nitori ere.


Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan