Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:8 - Bibeli Mimọ

8 Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Bí ẹ bá mú akọ mààlúù wá fún ọrẹ ẹbọ sísun, tabi fún ìrúbọ láti san ẹ̀jẹ́ tabi fún ẹbọ alaafia sí OLUWA,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “ ‘Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:8
10 Iomraidhean Croise  

Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA.


Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.


Ati ẹnikẹni ti o ba ru ẹbọ alafia si OLUWA, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá ni malu tabi agutan, ki o pé ki o ba le dà; ki o máṣe sí abùku kan ninu rẹ̀.


BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku.


Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA.


Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.


Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA.


Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò.


Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan