Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:4 - Bibeli Mimọ

4 Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 ẹni tí ó fẹ́ rúbọ yóo tọ́jú ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi idamẹrin òṣùnwọ̀n hini òróró kan pò fún ẹbọ ohun jíjẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná pẹ̀lú ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n òróró wá síwájú Olúwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:4
21 Iomraidhean Croise  

Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu.


Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin hini oróro ti a gún pòlu; ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ mimu, fun ọdọ-agutan ekini.


Nwọn o si mu gbogbo awọn arakunrin nyin lati orilẹ-ède gbogbo wá, ẹbọ kan si Oluwa lori ẹṣin, ati ninu kẹkẹ́, ati ninu páfa, ati lori ibaka, ati lori rakunmi, si Jerusalemu oke-nla mimọ́ mi; li Oluwa wi, gẹgẹ bi awọn ọmọ Israeli ti imu ọrẹ wá ninu ohun-elò mimọ́ sinu ile Oluwa.


Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa.


Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.


Ni ijọ́ kẹjọ ki o mú ọdọ-agutan meji akọ alailabùku wá, ati ọdọ-agutan kan abo ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa mẹta òṣuwọn deali iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati òṣuwọn logu oróro kan.


NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀.


Ki iwọ ki o si fi oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.


Ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ ki o jẹ́ meji idamẹwa òṣuwọn iyẹfun daradara, ti a fi oróro pò, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA fun õrun didùn: ati ẹbọ ohun-mimu rẹ̀ ni ki o ṣe ọtí-waini idamẹrin òṣuwọn hini.


Bi o ba mu ọdọ-agutan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:


Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ.


Nitori lati ilã-õrùn titi o si fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi; nibi gbogbo li a o si fi turàri jona si orukọ mi, pẹlu ọrẹ mimọ́: nitori orukọ mi o tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.


Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ:


Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ;


Pẹlu ẹbọ sisun oṣù, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu wọn, gẹgẹ bi ìlana wọn, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.


Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;


Ki emi ki o le ṣe iranṣẹ Jesu Kristi si awọn Keferi, lati ta ọrẹ ihinrere Ọlọrun, ki ọrẹ awọn Keferi ki o le di itẹwọgbà, ti a sọ di mimọ́ nipa Ẹmí Mimọ́.


Ṣugbọn ati mã ṣõre on ati mã pinfunni ẹ máṣe gbagbé: nitori irú ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ.


Ṣugbọn igi olifi wi fun wọn pe, Emi ha le fi ọrá mi silẹ, nipa eyiti nwọn nfi mi bù ọlá fun Ọlọrun ati enia, ki emi ki o si wá ṣe olori igi?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan