Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 15:3 - Bibeli Mimọ

3 Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 tí ẹ bá mú ninu agbo ẹran yín láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA tabi láti fi san ẹ̀jẹ́, tabi láti fi rú ẹbọ àtinúwá, tabi ẹbọ ní ọjọ́ àjọ yín, láti pèsè òórùn dídùn fún OLUWA;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 tí ẹ̀yin ó bá sì ṣe ẹbọ iná sí Olúwa ẹbọ sísun, tàbí ẹbọ, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá, tàbí nínú àjọ yín, láti ṣe òórùn dídùn sí Olúwa nínú agbo ẹran tàbí ọ̀wọ́ ẹran,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 15:3
27 Iomraidhean Croise  

OLUWA si gbọ́ õrun didùn; OLUWA si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ki yio si tun fi ilẹ ré nitori enia mọ́; nitori ìro ọkàn enia ibi ni lati ìgba ewe rẹ̀ wá; bẹ̃li emi ki yio tun kọlù ohun alãye gbogbo mọ́ bi mo ti ṣe.


Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu.


Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara.


Iwọ o si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ na: ẹbọ sisun ni si OLUWA: õrùn didùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.


Iwọ o si gbà wọn li ọwọ́ wọn, iwọ o si sun wọn lori pẹpẹ na li ẹbọ sisun, fun õrùn didùn niwaju OLUWA: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.


Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o pa rubọ li aṣalẹ, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi ẹbọ jijẹ owurọ̀, ati gẹgẹ bi ẹbọ mimu rẹ̀, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.


Ki ẹnyin ki o si jẹ ẹ ni ibi mimọ́, nitoripe ipín tirẹ, ati ipín awọn ọmọ rẹ ni, ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: nitoripe, bẹ̃li a fi aṣẹ fun mi.


Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ.


Ṣugbọn bi ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ba ṣe ti ẹjẹ́, tabi ọrẹ-ẹbọ atinuwá, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti o ru ẹbọ rẹ̀: ati ni ijọ́ keji ni ki a jẹ iyokù rẹ̀ pẹlu:


Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu meji, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan, ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA;


Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun si OLUWA fun õrùn didùn; ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan; ki nwọn ki o si jẹ́ alailabùku fun nyin:


Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn.


Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.


Nitori õrun didùn Kristi li awa jẹ fun Ọlọrun, ninu awọn ti a ngbalà, ati ninu awọn ti o nṣegbé:


Fun awọn kan, awa jẹ õrun ikú si ikú, ati fun awọn miran õrun iyè. Tali o ha si to fun nkan wọnyi?


Ẹ si mã rìn ni ifẹ, gẹgẹ bi Kristi pẹlu ti fẹ wa, ti o si fi ara rẹ̀ fun wa li ọrẹ ati ẹbọ fun Ọlọrun fun õrùn didun.


Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA.


Ki iwọ ki o máṣe jẹ idamẹwa ọkà rẹ ninu ibode rẹ, tabi ti ọti-waini rẹ, tabi ti oróro rẹ, tabi ti akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, tabi ti agbo-ẹran rẹ, tabi ti ẹjẹ́ rẹ ti iwọ jẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwa rẹ, tabi ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ rẹ:


Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o ma mú ẹbọ sisun nyin wá, ati ẹbọ nyin, ati idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ifẹ́-atinuwa nyin, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran nyin ati ti agbo-ẹran nyin:


Ṣugbọn mo ni ohun gbogbo, mo si ti di pupọ: mo si kún nigbati mo ti gbà nkan wọnni ti a ti rán lati ọdọ nyin wá lọwọ Epafroditu, ọrẹ olõrùn didùn, ẹbọ itẹwọgbà, ti iṣe inu didùn gidigidi si Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan