Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.
Ati agbọ̀n àkara alaiwu kan, àkara adidùn iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si, ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati ẹbọ ohunmimu wọn.