Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 14:4 - Bibeli Mimọ

4 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẹ jẹ ki a yàn olori, ki a si pada lọ si Egipti.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí, kí á pada sí Ijipti.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Ejibiti.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 14:4
11 Iomraidhean Croise  

Wipe, bẹ̃kọ̀; ṣugbọn awa fẹ lọ si ilẹ Egipti, nibiti awa kì yio ri ogun-kogun, ti a kì o si gbọ́ iró fère, ti ebi onjẹ kò ni ipa wa, nibẹ li awa o si mã gbe:


Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá?


Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli.


Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti;


Ṣugbọn on kò gbọdọ kó ẹṣin jọ fun ara rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe mu awọn enia pada lọ si Egipti, nitori ki o ba le kó ẹṣin jọ: nitori OLUWA ti wi fun nyin pe, Ẹnyin kò gbọdọ tun pada lọ li ọ̀na na mọ́.


OLUWA yio si fi ọkọ̀ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọ̀na ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ́: nibẹ̀ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkunrin ati ẹrú obinrin, ki yio si sí ẹniti yio rà nyin.


Ati nitõtọ, ibaṣepe nwọn fi ilu tí nwọn ti jade wa si ọkàn, nwọn iba ti ri aye lati pada.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan