Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 14:3 - Bibeli Mimọ

3 Nitori kini OLUWA ṣe mú wa wá si ilẹ yi, lati ti ipa idà ṣubu? Awọn aya wa, ati awọn ọmọ wa yio di ijẹ: kò ha san fun wa ki a pada lọ si Egipti?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Kí ló dé tí OLUWA fi ń mú wa lọ sí ilẹ̀ náà kí àwọn ọ̀tá wa lè pa wá, kí wọ́n sì kó àwọn aya ati àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní sàn fún wa kí á pada sí Ijipti?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 14:3
14 Iomraidhean Croise  

Nwọn si kọ̀ lati gbọràn, bẹ̃ni nwọn kò ranti iṣẹ iyanu ti iwọ ṣe li ãrin wọn; ṣugbọn nwọn mu ọrùn wọn le, ninu ìṣọtẹ wọn, nwọn yan olori lati pada si oko-ẹrú wọn: ṣugbọn iwọ li Ọlọrun ti o mura lati dariji, olore ọfẹ, ati alãnu, o lọra lati binu, o si ṣeun pipọ̀, o kò si kọ̀ wọn silẹ.


Igba melo-melo ni nwọn sọ̀tẹ si i li aginju, ti nwọn si bà a ninu jẹ ninu aṣálẹ!


Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi.


Nwọn si wi fun wọn pe, Ki OLUWA ki o wò nyin, ki o si ṣe idajọ; nitoriti ẹnyin mu wa di okú-õrùn li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀, lati fi idá lé wọn lọwọ lati pa wa.


Wipe, bẹ̃kọ̀; ṣugbọn awa fẹ lọ si ilẹ Egipti, nibiti awa kì yio ri ogun-kogun, ti a kì o si gbọ́ iró fère, ti ebi onjẹ kò ni ipa wa, nibẹ li awa o si mã gbe:


Oluwa ti sọ niti nyin, ẹnyin iyokù Juda, ẹ má lọ si Egipti: ẹ mọ̀ dajudaju pe emi ti jẹri si nyin li oni yi.


Nwọn si fà ahọn wọn bi ọrun fun eke; ṣugbọn nwọn kò ṣe akoso fun otitọ lori ilẹ, nitoripe nwọn ti inu buburu lọ si buburu nwọn kò si mọ̀ mi, li Oluwa wi.


Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá?


Ohun kekere ha ni ti iwọ mú wa gòke lati ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin wá, lati pa wa li aginjù, ti iwọ fi ara rẹ jẹ́ alade lori wa patapata?


Awọn enia si mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Awa iba kuku ti kú nigbati awọn arakunrin wa kú niwaju OLUWA!


Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.


Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti;


Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan