Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:8 - Bibeli Mimọ

8 On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe, ó rí àwòrán Olúwa Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:8
39 Iomraidhean Croise  

Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si.


Bi o ṣe ti emi ni emi o ma wò oju rẹ li ododo: àworan rẹ yio tẹ mi lọrun nigbati mo ba jí.


Emi o dẹ eti mi silẹ si owe: emi o ṣi ọ̀rọ ìkọkọ mi silẹ loju okùn dùru.


O si ṣe ti ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji, Mose sọ̀rọ, Ọlọrun si fi ãrá da a li ohùn.


Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworan ohun kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti ohun kan ti mbẹ ni isalẹ ilẹ, tabi ti ohun kan ti mbẹ ninu omi ni isalẹ̀ ilẹ.


OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na.


On si wi fun u pe, Emi o mu gbogbo ore mi kọja niwaju rẹ, emi o si pè orukọ OLUWA niwaju rẹ; emi o si ṣe ore-ọfẹ fun ẹniti emi nfẹ ṣe ore-ọfẹ fun, emi o si ṣe ãnu fun ẹniti emi o ṣe ãnu fun.


Nigbati emi o mú ọwọ́ mi kuro, iwọ o si ri akẹhinsi mi: ṣugbọn oju mi li a ki iri.


Nigbati Aaroni ati gbogbo awọn ọmọ Israeli ri Mose, kiyesi i, awọ oju rẹ̀ ndán; nwọn si bẹ̀ru lati sunmọ ọdọ rẹ̀.


Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn.


Tali ẹnyin o ha fi Ọlọrun we? tabi awòran kini ẹnyin o fi ṣe akàwe rẹ̀?


Tani ẹnyin o fi mi we, ti yio si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gba?


Ọmọ enia, pa alọ́ kan, si pa owe kan fun ile Israeli;


Nigbana ni mo wipe, A! Oluwa Ọlọrun, nwọn wi niti emi pe, Owe ki o npa yi?


Ati nipa woli kan ni Oluwa mu Israeli jade ni Egipti: nipa woli kan li a si pa on mọ.


Nwọn o si wi fun awọn ara ilẹ yi: nwọn sá ti gbọ́ pe iwọ OLUWA mbẹ lãrin awọn enia yi, nitoripe a ri iwọ OLUWA li ojukoju, ati pe awọsanma rẹ duro lori wọn, ati pe iwọ li o ṣaju wọn, ninu ọwọ̀n awọsanma nigba ọsán, ati ninu ọwọ̀n iná li oru.


Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.


Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá.


Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.


Ko si ẹniti o ri Ọlọrun rí; Ọmọ bíbi kanṣoṣo, ti mbẹ li õkan àiya Baba, on na li o fi i hàn.


Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin.


Ibaṣepe emi kò ti ṣe iṣẹ wọnni larin wọn, ti ẹlomiran kò ṣe ri, nwọn kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi nwọn ti ri, nwọn si korira ati emi ati Baba mi.


Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.


Ṣugbọn gbogbo wa nwò ogo Oluwa laisi iboju bi ẹnipe ninu awojiji, a si npawada si aworan kanna lati ogo de ogo, ani bi lati ọdọ Oluwa ti iṣe Ẹmí.


OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé wolĩ kan dide fun ọ lãrin rẹ, ninu awọn arakunrin rẹ, bi emi; on ni ki ẹnyin ki o fetisi;


Wolĩ kan kò si hù mọ́ ni Israeli bi Mose, ẹniti OLUWA mọ̀ li ojukoju,


Nitorina ki ẹnyin ki o ma kiyesara nyin gidigidi, nitoripe ẹnyin kò ri apẹrẹ kan li ọjọ́ ti OLUWA bá nyin sọ̀rọ ni Horebu lati ãrin iná wá:


Iwọ kò gbọdọ yá ere fun ara rẹ, tabi aworán apẹrẹ kan ti mbẹ loke ọrun, tabi ti mbẹ ni ilẹ nisalẹ, tabi ti mbẹ ninu omi ni isalẹ ilẹ:


Ẹniti iṣe aworan Ọlọrun ti a kò ri, akọbi gbogbo ẹda:


Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu.


Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin.


ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni.


Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;


Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye.


Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan