Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:3 - Bibeli Mimọ

3 Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Mose ni ó jẹ́ oníwà ìrẹ̀lẹ̀ jù ninu gbogbo ẹni tí ó wà láyé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 (Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:3
16 Iomraidhean Croise  

Oluwa gbé awọn onirẹlẹ soke: o rẹ̀ awọn enia buburu si ilẹyilẹ.


Nitori ti Oluwa ṣe inudidùn si awọn enia rẹ̀; yio fi igbala ṣe awọn onirẹlẹ li ẹwà.


OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade.


Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin.


Ẹ sọ fun ọmọbinrin Sioni pe, Kiyesi i, Ọba rẹ mbọ̀ wá sọdọ rẹ, o ni irẹlẹ, o joko lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ọmọ kẹtẹkẹtẹ.


Alabukún-fun li awọn ọlọkàn-tutù: nitori nwọn o jogún aiye.


ṢUGBỌN emi Paulu tikarami fi inu tutù ati ìwa pẹlẹ Kristi bẹ̀ nyin, emi ẹni irẹlẹ loju nyin nigbati mo wà larin nyin, ṣugbọn nigbati emi kò si, mo di ẹni igboiya si nyin.


Nitori mo ṣiro rẹ pe emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na.


Mo di wère nipa ṣiṣogo; ẹnyin li o mu mi ṣe e: nitoriti o tọ́ ti ẹ ba yìn mi: nitoriti emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na, bi emi kò tilẹ jamọ nkankan.


Ṣugbọn awa nṣe pẹlẹ lọdọ nyin, gẹgẹ bi abiyamọ ti ntọju awọn ọmọ on tikararẹ:


Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn.


Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan