Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:12 - Bibeli Mimọ

12 Emi bẹ̀ ọ máṣe jẹ ki o dabi ẹniti o kú, ẹniti àbọ ara rẹ̀ run tán nigbati o ti inu iya rẹ̀ jade.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Má jẹ́ kí ó dàbí ọmọ tí ó ti kú kí á tó bí i, tí apákan ara rẹ̀ sì ti jẹrà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:12
9 Iomraidhean Croise  

Tabi bi ọlẹ̀ ti a sin, emi kì ba ti si; bi ọmọ iṣẹnu ti kò ri imọlẹ.


Bi igbín ti a tẹ̀ rẹ́ ti o si ṣegbe: bi iṣẹnu obinrin, bẹ̃ni ki nwọn ki o má ṣe ri õrùn.


Aaroni si wi fun Mose pe, Yẽ, oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, máṣe kà ẹ̀ṣẹ na si wa lọrùn, eyiti awa fi wère ṣe, ati eyiti awa ti dẹ̀ṣẹ.


Mose si kigbe pè OLUWA, wipe, Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, mu u lara dá nisisiyi.


Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀.


Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin;


Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan