Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 12:1 - Bibeli Mimọ

1 A TI Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ òdi si Mose nitori obinrin ara Etiopia ti o gbé ni iyawo: nitoripe o gbé obinrin ara Etiopia kan ni iyawo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 12:1
19 Iomraidhean Croise  

Emi o si mu ọ fi OLUWA bura, Ọlọrun ọrun, ati Ọlọrun aiye, pe iwọ ki yio fẹ́ aya fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani, lãrin awọn ẹniti mo ngbé:


Oluwa mi si mu mi bura, wipe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ obinrin fun ọmọ mi ninu awọn ọmọbinrin ara Kenaani ni ilẹ ẹniti emi ngbé:


Rebeka si wi fun Isaaki pe, Agara aiye mi ma dá mi nitori awọn ọmọbinrin Heti, bi Jakobu ba fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Heti, bi irú awọn wọnyi yi iṣe ninu awọn ọmọbinrin ilẹ yi, aiye mi o ha ti ri?


Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti.


Njẹ alufa Midiani li ọmọbinrin meje, nwọn si wá, nwọn pọn omi, nwọn si kún ọkọ̀ imumi lati fi omi fun agbo-ẹran baba wọn.


O si dùn mọ́ Mose lati ma bá ọkunrin na gbé: on si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose.


Ki iwọ ki o má si ṣe fẹ́ ninu awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmokọnrin rẹ, ki awọn ọmọbinrin wọn ki o má ba ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ki nwọn ki o má ba mu ki awọn ọmọkunrin rẹ ki o ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn.


Opó, tabi obinrin ikọsilẹ, tabi ẹni-ibàjẹ́, tabi panṣaga, wọnyi ni on kò gbọdọ fẹ́: bikoṣe wundia ni ki o fẹ́ li aya lati inu awọn enia rẹ̀.


Nitori gbogbo awọn enia wọnyi ti o ti ri ogo mi, ati iṣẹ-àmi mi, ti mo ti ṣe ni Egipti ati li aginjù, ti nwọn si dan mi wò nigba mẹwa yi, ti nwọn kò si fetisi ohùn mi;


Nwọn si dide niwaju Mose, pẹlu ãdọtalerugba ọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, ijoye ninu ijọ, awọn olorukọ ninu ajọ, awọn ọkunrin olokikí:


Orukọ aya Amramu a si ma jẹ́ Jokebedi, ọmọbinrin Lefi, ti iya rẹ̀ bi fun Lefi ni Egipti: on si bi Aaroni, ati Mose, ati Miriamu arabinrin wọn fun Amramu.


Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ̀.


Ṣugbọn o dahùn o si wi fun ẹniti o sọ fun u pe, Tani iya mi? ati tani awọn arakunrin mi?


Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu.


Nitoripe awọn arakunrin rẹ̀ kò tilẹ gbà a gbọ́.


Njẹ mo ha di ọta nyin nitori mo sọ otitọ fun nyin bi?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan