Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:5 - Bibeli Mimọ

5 Awa ranti ẹja, ti awa ti njẹ ni Egipti li ọfẹ; ati apálà, ati bàra, ati ewebẹ, ati alubọsa, ati eweko:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Ejibiti, apálà, bàrà, ewébẹ̀, àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:5
7 Iomraidhean Croise  

Lọwọ awọn enia nipa ọwọ rẹ, Oluwa, lọwọ awọn enia aiye, ti nwọn ni ipin wọn li aiye yi, ati ikùn ẹniti iwọ fi ohun iṣura rẹ ìkọkọ kún: awọn ọmọ wọn pọ̀n nwọn a si fi iyokù ini wọn silẹ fun awọn ọmọ-ọwọ́ wọn.


Awọn ọmọ Israeli si wi fun wọn pe, Awa iba ti ti ọwọ́ OLUWA kú ni Egipti, nigbati awa joko tì ìkoko ẹran, ti awa njẹ ajẹyo; ẹnyin sá mú wa jade wá si ijù yi, lati fi ebi pa gbogbo ijọ yi.


Ọmọbinrin Sioni li a si fi silẹ bi agọ ninu ọgbà àjara, bi abule ninu ọgbà ẹ̀gúsí, bi ilu ti a dóti.


Wipe, bẹ̃kọ̀; ṣugbọn awa fẹ lọ si ilẹ Egipti, nibiti awa kì yio ri ogun-kogun, ti a kì o si gbọ́ iró fère, ti ebi onjẹ kò ni ipa wa, nibẹ li awa o si mã gbe:


Ṣugbọn lati igba ti awa ti fi sisun turari fun ayaba ọrun silẹ, ati lati da ẹbọ ohun mimu fun u, awa ti ṣalaini ohun gbogbo, a si run nipa idà ati nipa ìyan.


Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi!


Igbẹhin ẹniti iṣe iparun, ikùn ẹniti iṣe ọlọrun wọn, ati ogo ẹniti o wà ninu itiju wọn, awọn ẹniti ntọju ohun aiye.)


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan