Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:13 - Bibeli Mimọ

13 Nibo li emi o gbé ti mú ẹran wá fi fun gbogbo enia yi? nitoriti nwọn nsọkun si mi wipe, Fun wa li ẹran, ki awa ki o jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Níbo ni kí n ti rí ẹran tí yóo tó fún àwọn eniyan wọnyi? Wò ó! Wọ́n ń sọkún níwájú mi; wọ́n ń wí pé kí n fún àwọn ní ẹran jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Níbo ni n ó ti rí ẹran fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí? Nítorí wọ́n ń sọkún sí mi pé, ‘Fún wa lẹ́ran jẹ́!’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:13
9 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si da a lohùn wipe, Nibo li a ó gbé ti le fi akara tẹ́ awọn enia wọnyi lọrùn li aginjù yi?


Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo li awa o ti ri akara to li aginjù, ti yio fi yó ọ̀pọ enia yi?


Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́.


Mose si wipe, Awọn enia na, lãrin awọn ẹniti emi wà, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ ẹlẹsẹ̀; iwọ si wipe, Emi o fun wọn li ẹran, ki nwọn ki o le ma jẹ li oṣù kan tọ̀tọ.


Agbo-ẹran tabi ọwọ́-ẹran ni ki a pa fun wọn, lati tó fun wọn ni? tabi gbogbo ẹja okun li a o kójọ fun wọn lati tó fun wọn?


Ṣugbọn li oṣù kan tọ̀tọ, titi yio fi yọ jade ni ihò-imu nyin, ti yio si fi sú nyin: nitoriti ẹnyin gàn OLUWA ti mbẹ lãrin nyin, ẹnyin si sọkun niwaju rẹ̀, wipe, Ẽṣe ti awa fi jade lati Egipti wá?


Iranṣẹ rẹ̀ si wipe, Kinla, ki emi ki o gbé eyi kà iwaju ọgọrun enia? On si tun wipe, Fi fun awọn enia, ki nwọn ki o le jẹ: nitori bayi li Oluwa wi pe, Nwọn o jẹ, nwọn o si kù silẹ.


Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ ṣí ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan