Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:11 - Bibeli Mimọ

11 Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Mose bá wí fún OLUWA pé, “Kí ló dé tí o ṣe mí báyìí? Kí ló dé tí n kò rí ojurere rẹ, tí o sì di ẹrù gbogbo àwọn eniyan wọnyi rù mí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Mose sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé, “Kí ló dé tí o fi mú wàhálà yìí bá ìránṣẹ́ rẹ? Kí ni mo ṣe tí n kò fi tẹ ọ lọ́rùn tí ìwọ fi di ẹrù àwọn ènìyàn wọ̀nyí lé mi lórí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:11
16 Iomraidhean Croise  

Emi o wi fun Ọlọrun pe, o jare! máṣe dá mi lẹbi; fi hàn mi nitori idi ohun ti iwọ fi mba mi jà.


Oluwa, ibaṣepe iwọ a mã sami ẹ̀ṣẹ, Oluwa, tani iba duro?


Ki o má si ba ọmọ-ọdọ rẹ lọ sinu idajọ, nitori ti kò si ẹniti o wà lãye ti a o dalare niwaju rẹ.


Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta.


Mose si pada tọ̀ OLUWA lọ, o si wi fun u pe, OLUWA, ẽtiṣe ti o fi ṣe buburu si awọn enia yi bẹ̃? ẽtiṣe ti o fi rán mi?


Egbe ni fun mi, iyá mi, ti o bi mi ni ọkunrin ija ati ijiyan gbogbo aiye! emi kò win li elé, bẹ̃ni enia kò win mi li elé; sibẹ gbogbo wọn nfi mi ré.


Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro?


Ẹnyin ti wipe, Asan ni lati sìn Ọlọrun: anfani kili o si wà, ti awa ti pa ilàna rẹ̀ mọ, ti awa si ti rìn ni igbãwẹ̀ niwaju Oluwa awọn ọmọ-ogun?


Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.


Ati bi bayi ni iwọ o ṣe si mi, emi bẹ̀ ọ, pa mi kánkan, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ; má si ṣe jẹ ki emi ri òṣi mi.


Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ.


Emi o ti ṣe le nikan rù inira nyin, ati ẹrù nyin, ati ìja nyin?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan