Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 11:10 - Bibeli Mimọ

10 Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Mose gbọ́ bí àwọn eniyan náà ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ wọn, olukuluku pẹlu àwọn ará ilé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Mose, ibinu OLUWA sì ru sí àwọn eniyan náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Mose sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálùkù ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mose sì bàjẹ́ pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 11:10
19 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa.


Oluwa, njẹ emi kò korira awọn ti o korira rẹ? njẹ inu mi kò ha si bajẹ si awọn ti o dide si ọ?


Nitorina, Oluwa gbọ́ eyi, o binu: bẹ̃ni iná ràn ni Jakobu, ibinu si ru ni Israeli;


Nigbati Ọlọrun gbọ́ eyi, o binu, o si korira Israeli gidigidi.


Nitorina ni ibinu Oluwa fi ràn si enia rẹ̀, o si ti na ọwọ́ rẹ̀ si wọn, o si ti lù wọn: awọn òke si warìri, okú wọn si wà bi igbẹ li ãrin igboro. Ni gbogbo eyi ibinu rẹ̀ kò yi kuro, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ nà jade sibẹ.


Iwọ fun ara rẹ ni yio jọ̃ ogún rẹ lọwọ, ti mo ti fi fun ọ, emi o mu ọ sìn awọn ọta rẹ ni ilẹ ti iwọ kò mọ̀ ri: nitoriti ẹnyin ti tinabọ ibinu mi, ti yio jo lailai.


AWỌN enia na nṣe irahùn, nwọn nsọ ohun buburu li etí OLUWA: nigbati OLUWA si gbọ́ ọ, ibinu rẹ̀ si rú; iná OLUWA si ràn ninu wọn, o si run awọn ti o wà li opin ibudó na.


Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi?


Nigbati ìri ba si sẹ̀ si ibudó li oru, manna a bọ́ si i.


Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.


Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ.


Bẹ̃ni nwọn si gòke lọ kuro nibi agọ́ Kora, Datani ati Abiramu, ni ìha gbogbo: Datani ati Abiramu si jade, nwọn si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ wọn, ati awọn aya wọn, ati awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn wẹ́wẹ.


Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.


Ṣugbọn nigbati Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun.


Nigbati o si fi ibinu wò gbogbo wọn yiká, ti inu rẹ̀ bajẹ nitori lile àiya wọn, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si nà a: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.


Nitoripe iná kan ràn ninu ibinu mi, yio si jó dé ipò-okú ni isalẹ, yio si run aiye pẹlu asunkún rẹ̀, yio si tinabọ ipilẹ awọn okenla.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan