Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:21 - Bibeli Mimọ

21 Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Lẹ́yìn wọn ni àwọn ọmọ Kohati tí wọ́n ru àwọn ohun èlò mímọ́ tó ṣí. Èyí jẹ́ kí àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari rí ààyè láti pa Àgọ́ Àjọ náà kí àwọn ọmọ Kohati tó dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:21
11 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.


Wọnyi ni awọn ọmọ Lefi, bi ile baba wọn; ani olori awọn baba, bi a ti ka wọn ni iye orukọ, nipa ori wọn, awọn ti o ṣiṣẹ ìsin ile Oluwa, lati iwọn ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ.


Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.


A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí.


Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli.


Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn.


Ṣugbọn nwọn kò gbọdọ wọle lọ lati wò ohun mimọ́ ni iṣẹju kan, ki nwọn ki o má ba kú.


Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan