Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:2 - Bibeli Mimọ

2 Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 “Fi fadaka tí wọ́n fi òòlù lù ṣe fèrè meji fún pípe àwọn ọmọ Israẹli jọ ati títú ibùdó palẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:2
14 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn ninu owo ti a mu wá sinu ile Oluwa, a kò fi ṣe ọpọ́n fadakà, alumagàji fitila, awokoto, ipè ohun èlo wura tabi ohun elò fadakà kan fun ile Oluwa:


Awon ọmọ Lefi pẹlu ti iṣe akọrin, gbogbo wọn ti Asafu, ti Hemani, ti Jedutuni, pẹlu awọn ọmọ wọn ati awọn arakunrin wọn, nwọn wọ ọ̀gbọ funfun, nwọn ni kimbali, ati ohun-elo orin, ati duru, nwọn si duro ni igun ila-õrun pẹpẹ na, ati pẹlu wọn, ìwọn ọgọfa alufa ti nwọn nfún ipè:)


Ẹ fun ipè li oṣù titún, ni ìgbà ti a lana silẹ, li ọjọ ajọ wa ti o ni ironu.


Ibukún ni fun awọn enia ti o mọ̀ ohùn ayọ̀ nì: Oluwa, nwọn o ma rìn ni imọlẹ oju rẹ.


Iwọ o si ṣe kerubu wurà meji; ni iṣẹ lilù ni ki iwọ ki o fi ṣe wọn, ni ìku itẹ́-ãnu na mejeji.


Iwọ o si fi kìki wurà ṣe ọpá-fitila kan: iṣẹlilù li a o fi ṣe ọpá-fitila na, ipilẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀; ago rẹ̀, irudi rẹ̀, ati itanna rẹ̀, ọkanna ni nwọn o jẹ́:


Ẹ má mu ọrẹ asan wá mọ́: turari jasi ohun irira fun mi; oṣù titun ati ọjọ isimi, ìpe ajọ, emi kò le rọju gbà; ẹ̀ṣẹ ni, ani apèjọ ọ̀wọ nì.


Ẹ kede ni Juda, ki ẹ si pokikí ni Jerusalemu; ki ẹ si wipe, ẹ fun fère ni ilẹ na, ẹ ké, ẹ kojọ pọ̀, ki ẹ si wipe; Pè apejọ ara nyin, ki ẹ si lọ si ilu olodi wọnnì.


FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi.


Ẹ yà àwẹ kan si mimọ́, ẹ pè ajọ kan ti o ni irònu, ẹ pè awọn agbà, ati gbogbo awọn ará ilẹ na jọ si ile Oluwa Ọlọrun nyin, ki ẹ si kepe Oluwa,


Ẹ fun ipè ni Sioni, ẹ si dá idagìri ni oke mimọ́ mi; jẹ ki awọn ará ilẹ na warìri: nitoriti ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, nitori o kù si dẹ̀dẹ;


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri.


Oluwa kan, igbagbọ́ kan, baptismu kan,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan