Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 10:12 - Bibeli Mimọ

12 Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Àwọn ọmọ Israẹli sì gbéra kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù Parani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 10:12
22 Iomraidhean Croise  

Ati awọn ara Hori li oke Seiri wọn, titi o fi de igbo Parani, ti o wà niha ijù.


O si joko ni ijù Parani: iya rẹ̀ si fẹ́ obinrin fun u lati ilẹ Egipti wá.


Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.


Nwọn si mu ọ̀na-àjo wọn pọ̀n lati Sukkoti lọ, nwọn si dó si Etamu leti ijù.


Ọlọrun yio ti Temani wá, ati Ẹni Mimọ́ lati oke Parani. Ogo rẹ̀ bò awọn ọrun, ilẹ aiye si kun fun iyìn rẹ̀.


OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe,


Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn.


Lẹhin eyinì li awọn enia si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si ijù Parani.


Nwọn si lọ nwọn tọ̀ Mose wá, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ni ijù Parani, ni Kadeṣi; nwọn si mú ọ̀rọ pada tọ̀ wọn wá, ati gbogbo ijọ, nwọn si fi eso ilẹ na hàn wọn.


Mose si rán wọn lati ijù Parani lọ, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA: gbogbo awọn ọkunrin na jẹ́ olori awọn ọmọ Israeli.


Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.


OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe,


Nigbati awọsanma ba ká soke kuro lori agọ́ na, lẹhin na awọn ọmọ Israeli a si ṣí: nibiti awọsanma ba si duro, nibẹ̀ li awọn ọmọ Israeli idó si.


Nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla, oṣù kini, li aṣalẹ ni ijù Sinai: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe.


WỌNYI li ọ̀rọ ti Mose sọ fun gbogbo Israeli ni ìha ihin Jordani li aginjù, ni pẹtẹlẹ̀ ti o kọjusi Okun Pupa, li agbedemeji Parani, ati Tofeli, ati Labani, ati Haserotu, ati Disahabu.


Nigbati awa si kuro ni Horebu, awa rìn gbogbo aginjù nla nì ti o ni ẹ̀ru já, ti ẹnyin ri li ọ̀na òke awọn ọmọ Amori, bi OLUWA Ọlọrun wa ti fun wa li aṣẹ; awa si wá si Kadeṣi-barnea.


Ẹ yipada, ki ẹnyin si mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo àgbegbe rẹ̀, ni pẹtẹlẹ̀, li ori òke, ati li afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati si Lebanoni, dé odò nla nì, odò Euferate.


O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá.


SAMUELI si kú; gbogbo enia Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn sì sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ninu ile rẹ̀ ni Rama. Dafidi si dide, o si sọkalẹ lọ si ijù Parani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan