Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:51 - Bibeli Mimọ

51 Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

51 OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

51 Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, àwọn ọmọ Lefi ni yóò tú palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Lefi náà ni yóò ṣe é. Àlejò tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:51
15 Iomraidhean Croise  

Ibinu Oluwa si ru si Ussa; Ọlọrun si pa a nibẹ nitori iṣiṣe rẹ̀; nibẹ li o si kú li ẹba apoti-ẹri Ọlọrun.


O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí.


Lati ma ṣe ohun iranti fun awọn ọmọ Israeli, ki alejò kan, ti ki iṣe irú-ọmọ Aaroni, ki o máṣe sunmọtosi lati mú turari wá siwaju OLUWA; ki o má ba dabi Kora, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀: bi OLUWA ti wi fun u lati ọwọ́ Mose wá.


Ẹnikẹni ti o ba sunmọ agọ́ OLUWA yio kú: awa o ha fi kikú run bi?


Yio si ṣe, ọpá ẹniti emi o yàn yio ruwe: emi o si da kikùn awọn ọmọ Israeli duro kuro lọdọ mi, ti nwọn nkùn si nyin.


Awọn ọmọ Israeli kò si gbọdọ sunmọ agọ́ ajọ, ki nwọn ki o má ba rù ẹ̀ṣẹ, ki nwọn má ba kú.


Ki nwọn ki o ma pa aṣẹ rẹ mọ́, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju gbogbo agọ́, kìki pe nwọn kò gbọdọ sunmọ ohun-èlo ibi-mimọ́ ati pẹpẹ, ki ati awọn, ati ẹnyin pẹlu ki o má ba kú.


Ki nwọn ki o si dàpọ pẹlu rẹ, ki nwọn ki o si ma ṣe itọju agọ́ ajọ, gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ-ìsin agọ́: alejò kan kò sí gbọdọ sunmọ ọdọ nyin.


Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.


Ki iwọ ki o si yàn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma duro si iṣẹalufa wọn: alejò ti o ba si sunmọtosi pipa ni ki a pa a.


Ṣugbọn awọn ti o pagọ́ niwaju agọ́ na, si ìha ìla-õrùn, ani niwaju agọ́ ajọ si ìha ìla-õrùn ni, ki o jẹ́ Mose, ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn nṣe itọju ibi-mimọ́, fun itọju awọn ọmọ Israeli; alejò ti o ba si sunmọtosi pipa li a o pa a.


On si pọn awọn ọkunrin Betṣemeṣi loju, nitoriti nwọn bẹ inu apoti Oluwa wò, iye wọn ti o pa ninu awọn enia na jẹ ẹgbã mẹdọgbọn o le ãdọrin ọkunrin, awọn enia na pohunrere ẹkun nitoriti Oluwa fi iparun nla pa ọpọ̀ awọn enia na run.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan