Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:3 - Bibeli Mimọ

3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli, iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ìwọ ati Aaroni, ẹ ka gbogbo àwọn tí wọ́n lè jáde lọ sí ojú ogun, láti ẹni ogún ọdún lọ sókè. Ẹ kà wọ́n ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:3
16 Iomraidhean Croise  

Joabu si fi iye ti awọn enia na jasi le ọba lọwọ: o si jẹ oji ọkẹ ọkunrin alagbara ní Israeli, awọn onidà: awọn ọkunrin Juda si jẹ ọkẹ mẹ̃dọgbọn enia.


Awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ninu awọn ọkunrin alagbara ti nwọn ngbé asà ati idà, ti nwọn si nfi ọrun tafà, ti nwọn si mòye ogun, jẹ ọkẹ meji enia o le ẹgbẹrinlelogún o di ogoji, ti o jade lọ si ogun na.


Amasiah si kó Juda jọ, o si tò wọn lẹsẹsẹ gẹgẹ bi ile baba wọn, awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati balogun ọrọrun, ani gbogbo Juda ati Benjamini, o si ka iye wọn lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̀ lọ, o si ri wọn li ọkẹ mẹdogun enia ti a yàn, ti o le jade lọ si ogun, ti o si le lo ọ̀kọ ati asà.


Ẹ o si kiyesi ajọ aiwukàra; nitori li ọjọ́ na gan ni mo mú ogun nyin jade kuro ni ilẹ Egipti; nitorina ni ki ẹ ma kiyesi ọjọ́ na ni iran-iran nyin nipa ìlana lailai.


Olukuluku ẹniti o ba kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, ni yio fi ọrẹ fun OLUWA.


Abọ ṣekeli kan li ori ọkunrin kọkan, ni ìwọn ṣekeli ibi mimọ́, lori ori olukuluku ti o kọja sinu awọn ti a kà, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ le ẹgbẹtadilogun o le ãdọjọ enia.


Okú nyin yio ṣubu li aginjù yi; ati gbogbo awọn ti a kà ninu nyin, gẹgẹ bi iye gbogbo nyin, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jú bẹ̃ lọ, ti ẹ kùn si mi,


Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli.


Kaye awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ile baba wọn, nipa idile wọn: gbogbo ọkunrin lati ẹni oṣù kan lọ ati jù bẹ̃ lọ, ni ki iwọ ki o kà wọn.


Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti o gòke lati Egipti wá, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ki yio ri ilẹ na ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu: nitoriti nwọn kò tẹle mi lẹhin patapata.


WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni.


Lati ẹni ọgbọ̀n ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, ani titi di ẹni ãdọta ọdún, gbogbo ẹniti o wọ̀ inu iṣẹ-ìsin, lati ṣe iṣẹ ninu agọ́ ajọ.


Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn.


Mo si fun nyin li aṣẹ ni ìgbana, wipe, OLUWA Ọlọrun nyin ti fi ilẹ yi fun nyin lati ní i: ẹnyin o si kọja si ìha keji ni ihamọra ogun niwaju awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn akọni ọkunrin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan