Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:18 - Bibeli Mimọ

18 Nwọn si pè gbogbo ijọ enia pọ̀ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si pìtan iran wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ori wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn ọkunrin mejila náà, wọ́n kọ orúkọ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀, láti ẹni ogún ọdún sókè, ní agbo-ilé agbo-ilé, ati ní ìdílé-ìdílé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:18
7 Iomraidhean Croise  

Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe:


Awọn wọnyi li o si goke lati Telhariṣa, Kerubu, Addoni, ati Immeri wá: ṣugbọn nwọn kò le fi ile baba wọn hàn, tabi iran wọn, bi nwọn iṣe ti Israeli.


Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni.


OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe,


Ati Mose ati Aaroni mú awọn ọkunrin wọnyi ti a pè li orukọ:


Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi.


Ṣugbọn on ẹniti a kò tilẹ pitan iran rẹ̀ lati ọdọ wọn wá, ti gbà idamẹwa lọwọ Abrahamu, o si ti sure fun ẹniti o gbà ileri.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan