Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 1:1 - Bibeli Mimọ

1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdún keji, ti nwọn jade lati ilẹ Egipti wá, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 1:1
15 Iomraidhean Croise  

O si ṣe, ni ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹ̀rẹ si ikọ́ ile fun Oluwa.


LI oṣù kẹta, ti awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti tán, li ọjọ́ na gan ni nwọn dé ijù Sinai.


Nwọn sá ti ṣi kuro ni Refidimu, nwọn si wá si ijù Sinai, nwọn si dó si ijù na; nibẹ̀ ni Israeli si dó si niwaju oke na.


Nibẹ̀ li emi o ma pade rẹ, emi o si ma bá ọ sọ̀rọ lati oke itẹ́-ãnu wá, lati ãrin awọn kerubu mejeji wá, ti o wà lori apoti ẹrí na, niti ohun gbogbo ti emi o palaṣẹ fun ọ si awọn ọmọ Israeli.


O si ṣe li oṣù kini li ọdún keji ni ijọ́ kini oṣù na, ni a gbé agọ́ na ró.


Li ọjọ́ kini oṣù kini ni ki iwọ ki o gbé ibugbé agọ́ na ró.


OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe,


Wọnyi li ofin, ti OLUWA palaṣẹ fun Mose fun awọn ọmọ Israeli li òke Sinai.


Nwọn si pè gbogbo ijọ enia pọ̀ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si pìtan iran wọn gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ori wọn.


OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade.


OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, li oṣù kini ọdún keji ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe,


O si ṣe nigbati o di ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fun u li aṣẹ fun wọn;


Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn.


Nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ ti bukún ọ ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo: o ti mọ̀ ìrin rẹ li aginjù nla yi: li ogoji ọdún yi OLUWA Ọlọrun rẹ ti mbẹ pẹlu rẹ; ọdá ohun kan kò dá ọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan