Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:4 - Bibeli Mimọ

4 Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:4
15 Iomraidhean Croise  

Emi o wẹ̀ ọwọ mi li ailẹṣẹ: bẹ̃li emi o si yi pẹpẹ rẹ ká, Oluwa.


Ẹ wẹ̀, ki ẹ mọ́; mu buburu iṣe nyin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu;


Mo si gbe ìkoko ti o kún fun ọti-waini pẹlu ago, ka iwaju awọn ọmọ ile Rekabu, mo si wi fun wọn pe: Ẹ mu ọti-waini.


Jerusalemu! wẹ ọkàn rẹ kuro ninu buburu, ki a ba le gba ọ là. Yio ti pẹ to ti iro asan yio wọ̀ si inu rẹ.


Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nfọ̀ ode ago ati awopọkọ́ mọ́, ṣugbọn inu wọn kún fun irẹjẹ ati wọ̀bia.


Iwọ afọju Farisi, tetekọ fọ̀ eyi ti mbẹ ninu ago ati awopọkọ́ mọ́ na, ki ode wọn ki o le mọ́ pẹlu.


Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o.


Nitoriti ẹnyin fi ofin Ọlọrun si apakan, ẹnyin nfiyesi ofin atọwọdọwọ ti enia, bi irú wiwẹ̀ ohun-èlo ati ago: ati irú ohun miran pipọ bẹ̃ li ẹnyin nṣe.


Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta.


Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu.


Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.


Ẹ sunmọ Ọlọrun, on o si sunmọ nyin, Ẹ wẹ̀ ọwọ́ nyin mọ́, ẹnyin ẹlẹṣẹ; ẹ si ṣe ọkàn nyin ni mimọ́, ẹnyin oniye meji.


Ṣugbọn bi awa ba nrìn ninu imọlẹ, bi on ti mbẹ ninu imọlẹ, awa ní ìdapọ pẹlu ara wa, ẹ̀jẹ Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀ ni nwẹ̀ wa nù kuro ninu ẹṣẹ gbogbo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan