Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:3 - Bibeli Mimọ

3 Nitori awọn Farisi, ati gbogbo awọn Ju, bi nwọn ko ba wẹ̀ ọwọ́ wọn gidigidi, nwọn ki ijẹun, nitoriti nwọn npa ofin atọwọdọwọ awọn àgba mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 (Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:3
10 Iomraidhean Croise  

Ẹnyin nfi ofin atọwọdọwọ ti nyin, ti ẹ fi le ilẹ, sọ ọ̀rọ Ọlọrun di asan; ati ọpọ iru nkan bẹ̃ li ẹnyin nṣe.


Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun?


Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun.


Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta.


Mo si ta ọpọlọpọ awọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ ninu isin awọn Ju larin awọn ara ilu mi, mo si ni itara lọpọlọpọ si ofin atọwọdọwọ awọn baba mi.


Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi.


Niwọnbi ẹnyin ti mọ̀ pe, a kò fi ohun ti idibajẹ rà nyin pada, bi fadaka tabi wura, kuro ninu ìwa asan nyin, ti ẹnyin ti jogun lati ọdọ awọn baba nyin,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan