Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 7:2 - Bibeli Mimọ

2 Nigbati nwọn ri omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nfi ọwọ aimọ́ jẹun, eyini ni li aiwẹ̀ ọwọ́, nwọn mba wọn wijọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 7:2
12 Iomraidhean Croise  

Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ fi nrú ofin atọwọdọwọ awọn alàgba? nitoriti nwọn kì iwẹ̀ ọwọ́ wọn nigbati nwọn ba njẹun.


Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun?


Nigbati Farisi na si ri i, ẹnu yà a nitoriti kò kọ́ wẹ̀ ki o to jẹun.


O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́.


Ṣugbọn mo dahùn wipe, Agbẹdọ, Oluwa: nitori ohun èwọ tabi alaimọ́ kan kò wọ̀ ẹnu mi ri lai.


Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun.


Melomelo ni ẹ ro pe a o jẹ oluwa rẹ̀ ni ìya kikan, ẹniti o ti tẹ Ọmọ Ọlọrun mọlẹ ti o si ti kà ẹ̀jẹ̀ majẹmu ti a fi sọ ọ di mimọ́ si ohun aimọ́, ti o si ti kẹgan Ẹmí ore-ọfẹ.


Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan