Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:4 - Bibeli Mimọ

4 O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn lọ, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ bá wá, wọ́n ṣà á jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:4
8 Iomraidhean Croise  

Nigbati awọn ẹiyẹ si sọkalẹ wá si ori okú wọnyi, Abramu lé wọn kuro.


Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na.


Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.


Awọn wọnyi si ni ti ẹba ọ̀na, nibiti a funrugbin ọ̀rọ na; nigbati nwọn si ti gbọ́, lojukanna Satani wá, o si mu ọ̀rọ na ti a fọn si àiya wọn kuro.


Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin;


Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ:


Awọn ti ẹba ọ̀na li awọn ti o gbọ́; nigbana li Èṣu wá o si mu ọ̀rọ na kuro li ọkàn wọn, ki nwọn ki o má ba gbagbọ́, ki a ma ṣe gbà wọn là.


Afunrugbin kan jade lọ lati fun irugbin rẹ̀: bi o si ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na; a si tẹ̀ ẹ mọlẹ, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ṣà a jẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan