Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 4:3 - Bibeli Mimọ

3 Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ọkunrin kan jáde lọ láti fúnrúgbìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 4:3
29 Iomraidhean Croise  

Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa.


Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ!


Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi.


Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi:


Ni kutukutu fún irugbin rẹ, ati li aṣãlẹ máṣe da ọwọ rẹ duro: nitori ti iwọ kò mọ̀ eyi ti yio ṣe rere, yala eyi tabi eyini, tabi bi awọn mejeji yio dara bakanna.


Gbọ́ ti emi, ẹnyin alagidi ọkàn, ti o jinà si ododo:


Gbọ́ ti emi, iwọ ile Jakobu, ati gbogbo iyoku ile Israeli, ti mo ti gbe lati inu wá, ti mo ti rù lati inu iyá wá.


Owe miran li o pa fun wọn, wipe: Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀:


Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu.


O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin;


Afunrugbin funrugbin ọ̀rọ na.


O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe,


Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.


O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.


O si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ, ki o gbọ́.


Ṣugbọn Peteru dide duro pẹlu awọn mọkanla iyokù, o gbé ohùn rẹ̀ soke, o si wi fun wọn gbangba pe, Ẹnyin enia Judea, ati gbogbo ẹnyin ti ngbé Jerusalemu, ki eyiyi ki o yé nyin, ki ẹ si fetísi ọ̀rọ mi:


NJẸ nisisiyi Israeli, fetisi ìlana ati idajọ, ti emi nkọ́ nyin, lati ṣe wọn; ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹ si lọ igba ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin fi fun nyin.


Ẹ fi etí silẹ, ẹnyin ará mi olufẹ, Ọlọrun kò ha ti yàn awọn talakà aiye yi ṣe ọlọrọ̀ ni igbagbọ́, ati ajogun ijọba na, ti o ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ?


Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun kì yio farapa ninu ikú keji.


Ẹniti o ba li eti, ki o gbọ́ ohun ti Ẹmi nsọ fun awọn ijọ.


Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́ ohun ti Ẹmí nsọ fun awọn ijọ. Ẹniti o ba ṣẹgun ni emi o fi eso igi ìye nì fun jẹ, ti mbẹ larin Paradise Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan