Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 3:2 - Bibeli Mimọ

2 Nwọn si nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le fi i sùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Àwọn kan wà tí wọn ń ṣọ́ ọ bí yóo wo ọkunrin yìí sàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, kí wọn lè fi í sùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 3:2
12 Iomraidhean Croise  

Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a.


Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀.


Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.


Si kiyesi i, ọkunrin kan wà nibẹ̀, ti ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. Nwọn si bi i pe, O ha tọ́ lati mu-ni-larada li ọjọ isimi? ki nwọn ki o le fẹ ẹ li ẹfẹ̀.


O si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, duro larin.


O si ṣe, nigbati o wọ̀ ile ọkan ninu awọn olori Farisi lọ li ọjọ isimi lati jẹun, nwọn si nṣọ ọ.


Nwọn si nṣọ ọ, nwọn si rán awọn amí ti nwọn jẹ ẹlẹtan fi ara wọn pe olõtọ enia, ki nwọn ki o le gbá ọ̀rọ rẹ̀ mu, ki nwọn ki o le fi i le agbara ati aṣẹ Bãlẹ.


Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn.


Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ.


Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan