Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 2:8 - Bibeli Mimọ

8 Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Lójúkan náà bí Jesu tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yìn fi ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 2:8
23 Iomraidhean Croise  

Emi mọ̀ pẹlu, Ọlọrun mi, pe iwọ ndan ọkàn wò, iwọ si ni inudidún si ododo. Bi o ṣe ti emi, ninu ododo ọkàn mi li emi ti fi tinutinu ṣe iranlọwọ gbogbo nkan wọnyi; ati nisisiyi pẹlu ayọ̀ ni mo ti ri awọn enia rẹ ti o wá nihin, lati fi tinutinu ṣe iranlọwọ fun ọ.


Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére.


Ìro inu enia buburu, irira ni loju Oluwa; ṣugbọn mimọ́ ni ọ̀rọ didùn niwaju rẹ̀.


Ironu wère li ẹ̀ṣẹ; irira ninu enia si li ẹlẹgàn.


Jẹ ki enia buburu kọ̀ ọ̀na rẹ̀ silẹ, ki ẹ̀lẹṣẹ si kọ̀ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa, on o si ṣãnu fun u, ati si Ọlọrun wa, yio si fi jì li ọpọlọpọ.


Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; yio si ṣe pe nigbakanna ni nkan yio sọ si ọ̀kàn rẹ, iwọ o si rò èro ibi kan.


Nigbati Jesu ṣi mọ̀, o yẹ̀ ara rẹ̀ kuro nibẹ̀; ọ̀pọ ijọ enia tọ̀ ọ lẹhin, o si mu gbogbo wọn larada.


Nwọn si mbá ara wọn ṣaroye, wipe, Nitoriti awa ko mu akara lọwọ ni.


Jesu si mọ̀ ìro inu wọn, o wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe nrò buburu ninu nyin?


Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun?


Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?


Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania,


O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ara nyin kò lelẹ̀? ẽsitiṣe ti ìrokuro fi nsọ ninu ọkàn nyin?


Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin?


Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro.


O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.


Ṣugbọn awọn kan wà ninu nyin ti kò gbagbọ́. Nitori Jesu mọ̀ lati ìbẹrẹ wá ẹniti nwọn iṣe ti ko gbagbọ́, ati ẹniti yio fi on hàn.


Ṣugbọn Peteru wipe, Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmí Mimọ́, ti iwọ si fi yàn apakan pamọ́ ninu owo ilẹ na?


Nitorina ronupiwada ìwa buburu rẹ yi, ki o si gbadura sọdọ Ọlọrun, boya yio dari ete ọkàn rẹ jì ọ.


Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.


Emi o si fi ikú pa awọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ijọ ni yio si mọ̀ pe, emi li ẹniti nwadi inu ati ọkàn: emi o si fifun olukuluku nyin gẹgẹ bi iṣẹ nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan