Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 2:12 - Bibeli Mimọ

12 O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Lójúkan náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé àkéte rẹ̀. Ó sì jáde lọ lójú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 2:12
13 Iomraidhean Croise  

Ẹnu si yà gbogbo enia, nwọn si wipe, Ọmọ Dafidi kọ́ yi?


Tobẹ̃, ti ẹnu yà ijọ enia na, nigbati nwọn ri ti odi nfọhùn, ti arọ ndi ọ̀tọtọ, ti amukun nrìn, ti afọju si nriran: nwọn si yìn Ọlọrun Israeli logo.


Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli.


Nigbati ijọ enia si rí i, ẹnu yà wọn, nwọn yìn Ọlọrun logo, ti o fi irú agbara bayi fun enia.


Hà si ṣe gbogbo wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi mbi ara wọn lẽre, wipe, Kili eyi? ẹkọ́ titun li eyi? nitoriti o fi agbara paṣẹ fun awọn ẹmi aimọ́, nwọn si gbọ́ tirẹ̀.


Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ.


O si fi ọwọ́ rẹ̀ le e: lojukanna a si ti sọ ọ di titọ, o si nyìn Ọlọrun logo.


Nigbati ọkan ninu wọn ri pe a mu on larada o pada, o si fi ohùn rara yin Ọlọrun logo.


Ẹnu si yà gbogbo wọn, nwọn si nyìn Ọlọrun logo, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwipe, Awa ri ohun abàmi loni.


Ẹ̀rù si ba gbogbo wọn: nwọn si nyìn Ọlọrun logo, wipe, Woli nla dide ninu wa; ati pe, Ọlọrun si wa ibẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò.


Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe?


Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí.


Nigbati nwọn si kìlọ fun wọn si i, nwọn jọwọ wọn lọwọ lọ, nigbati nwọn kò ti ri nkan ti nwọn iba fi jẹ wọn ni ìya, nitori awọn enia: nitori gbogbo wọn ni nyìn Ọlọrun logo fun ohun ti a ṣe.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan