Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 2:1 - Bibeli Mimọ

1 NIGBATI o si tún wọ̀ Kapernaumu lọ lẹhin ijọ melokan; okikí kàn yiká pe, o wà ninu ile.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Jesu tún lọ sí Kapanaumu, àwọn eniyan gbọ́ pé ó wà ninu ilé kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 2:1
13 Iomraidhean Croise  

Nigbati o si jade kuro ni Nasareti, o wá ijoko ni Kapernaumu, eyi ti o mbẹ leti okun li ẹkùn Sebuloni ati Neftalimu:


O si bọ sinu ọkọ̀, o rekọja, o si wá si ilu on tikararẹ̀.


Ṣugbọn o jade, o si bẹrẹ si ikokiki, ati si itàn ọ̀ran na kalẹ, tobẹ̃ ti Jesu kò si le wọ̀ ilu ni gbangba mọ́, ṣugbọn o wà lẹhin odi nibi iju: nwọn si tọ̀ ọ wá lati ìha gbogbo wá.


Lojukanna ọ̀pọ enia si pejọ tobẹ̃ ti aye kò si fun wọn mọ, kò si, titi de ẹnu-ọ̀na: o si wasu ọ̀rọ na fun wọn.


Ijọ enia si tún wọjọ pọ̀, ani tobẹ̃ ti nwọn ko tilẹ le jẹ onjẹ.


Nigbati o si ti ọdọ awọn enia kuro wọ̀ inu ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre niti owe na.


O si dide ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni, o si wọ̀ inu ile kan, ko si fẹ ki ẹnikẹni ki o mọ̀: ṣugbọn on kò le fi ara pamọ́.


Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade?


O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o pa owe yi si mi pe, Oniṣegun, wò ara rẹ sàn: ohunkohun ti awa gbọ́ pe o ti ọwọ́ rẹ ṣe ni Kapernaumu, ṣe e nihinyi pẹlu ni ilẹ ara rẹ.


Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀.


Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Judea wá si Galili, o tọ̀ ọ wá, o si mbẹ̀ ẹ, ki o le sọkalẹ wá ki o mu ọmọ on larada: nitoriti o wà li oju ikú.


Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan