Marku 12:2 - Bibeli Mimọ2 Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn oluṣọgba na, ki o le gbà ninu eso ọgba ajara na lọwọ awọn oluṣọgba. Faic an caibideilYoruba Bible2 Nígbà tí ó tó àkókò, ó rán ẹrú rẹ̀ kan lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alágbàro náà pé, kí ó lọ gbà ninu èso àjàrà wá lọ́wọ́ wọn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. Faic an caibideil |
Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.