Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 10:1 - Bibeli Mimọ

1 O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà, Jesu kúrò níbẹ̀, ó sì wá sí ẹkùn Judea níhà òkè odò Jordani. Àwọn ènìyàn sì tún tọ̀ ọ́ wá, bí i ìṣe rẹ̀, ó sì kọ́ wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 10:1
17 Iomraidhean Croise  

Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ.


Nwọn si ti yi ẹhin wọn pada si mi, kì isi ṣe oju: emi kọ́ wọn, mo ndide ni kutukutu lati kọ́ wọn, sibẹ nwọn kò fetisilẹ lati gbà ẹkọ.


Ni wakati na ni Jesu wi fun ijọ enia pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? li ojojumọ li emi mba nyin joko ni tẹmpili ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si gbé ọwọ́ le mi.


Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.


Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni.


Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ?


Bi Jesu si ti nkọ́ni ni tẹmpili, o dahùn wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi iṣe?


Li ojojumọ li emi wà pẹlu nyin ni tẹmpili, ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si mu mi: ṣugbọn iwe-mimọ kò le ṣe alaiṣẹ.


O si tún jade lọ si eti okun; gbogbo ijọ enia si wá sọdọ rẹ̀, o si kọ́ wọn.


O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe,


Nigbati o si di ọjọ isimi, o bẹ̀rẹ si ikọni ninu sinagogu; ẹnu si yà awọn enia pipọ ti o gbọ́, nwọn wipe, Nibo li ọkunrin yi gbé ti ri nkan wọnyi? irú ọgbọ́n kili eyi ti a fifun u, ti irú iṣẹ agbara bayi nti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?


Nigbati Jesu jade, o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti nwọn dabi awọn agutan ti kò li oluṣọ: o si bẹ̀rẹ si ima kọ́ wọn li ohun pipọ.


Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni.


O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko.


Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea.


Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan