Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Marku 1:1 - Bibeli Mimọ

1 IBẸRẸ ihinrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Marku 1:1
23 Iomraidhean Croise  

Emi o si rohin ipinnu Oluwa: O ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bi ọ.


Nigbana li awọn ti mbẹ ninu ọkọ̀ wá, nwọn si fi ori balẹ fun u, wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun ni iwọ iṣe.


Bi o ti nwi lọwọ, wo o, awọsanma didán ṣiji bò wọn: si wo o, ohùn kan lati inu awọsanma wá, ti o wipe, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi; ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.


Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.


Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara.


Angẹli na si dahùn o si wi fun u pe, Ẹmí Mimọ́ yio tọ̀ ọ wá, ati agbara Ọgá-ogo yio ṣiji bò ọ: nitorina ohun mimọ́ ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun li a o ma pè e.


Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Emi si ti ri, emi si ti njẹri pe, Eyi li Ọmọ Ọlọrun.


Natanaeli dahùn, o si wi fun u pe, Rabbi, iwọ li Ọmọ Ọlọrun; iwọ li Ọba Israeli.


Ṣugbọn wọnyi li a kọ, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe, Jesu ni iṣe Kristi na, Ọmọ Ọlọrun; ati ni gbigbàgbọ́, ki ẹnyin ki o le ni ìye li orukọ rẹ̀.


Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.


Awa si ti gbagbọ́, a si mọ̀ pe, iwọ ni Kristi na, Ọmọ Ọlọrun alãye.


Bẹ̀rẹ lati igba baptismu Johanu wá, titi o fi di ọjọ na ti a gbé e lọ soke kuro lọdọ wa, o yẹ ki ọkan ninu awọn wọnyi ṣe ẹlẹri ajinde rẹ̀ pẹlu wa.


Nigbati Johanu ti kọ́ wãsu baptismu ironupiwada fun gbogbo enia Israeli ṣaju wíwa rẹ̀.


Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara:


Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan