Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Luku 9:3 - Bibeli Mimọ

3 O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe mu nkan lọ fun àjo nyin, ọpá, tabi àpo tabi akara, tabi owo; bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe ni àwọtẹlẹ meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkankan lọ́wọ́ lọ ìrìn àjò yìí: ẹ má mú ọ̀pá lọ́wọ́, tabi àpò báárà tabi oúnjẹ tabi owó, tabi àwọ̀tẹ́lẹ̀ meji.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó: bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Luku 9:3
12 Iomraidhean Croise  

Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ.


O si pè awọn mejila na sọdọ rẹ̀, o bẹ̀rẹ si irán wọn lọ ni meji-meji; o si fi aṣẹ fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́;


O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora.


Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere?


O si wi fun wọn pe, Nigbati mo rán nyin lọ laini asuwọn, ati àpo, ati bàta, ọdá ohun kan da nyin bi? Nwọn si wipe, Rara o.


O dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li ẹ̀wu meji, ki o fi ọkan fun ẹniti kò ni; ẹniti o ba si li onjẹ, ki o ṣe bẹ̃ pẹlu.


Lefi si se àse nla fun u ni ile rẹ̀: ọ̀pọ ijọ awọn agbowode, ati awọn ẹlomiran mbẹ nibẹ̀ ti nwọn ba wọn joko.


Ni ilekile ti ẹnyin ba si wọ̀, nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o gbé, lati ibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ti jade.


Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan